JANUARY 21, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ìjì Lílé Ṣọṣẹ́ Láwọn Agbègbè Kan Lórílẹ́-èdè Amẹ́ríkà
Ní January 11 àti 12, 2020, Ìjì lílé kan jà, ó sì ṣọṣẹ́ làwọn agbègbè kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọṣẹ́ kékeré kọ́ ní àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò, ìjì tó fẹ́ atẹ́gùn àti ìjì líle tó ṣẹlẹ̀ fún odindi ọjọ́ méjì ṣe ní ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ lórílẹ̀-èdè yẹn. Ó bani nínú jẹ́ pé Arákùnrin Albert Barnett ẹni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún (85) àti ìyàwó rẹ̀, Arábìnrin Susan Barnett, tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) kú nígbà tí ìjì líle náà kọlu ilé wọn.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ròyìn pé, ó kéré tán ilé àwọn ará wa mẹ́rin àti Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì ni ìjì náà kọlù, àmọ́ àwọn ilé náà kò fi bẹ́ẹ̀ bà jẹ́ púpọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìjì líle náà ba ilé tí arákùnrin wa kan ti ń tajà jẹ́ gan-an.
Àwọn alàgbà àtàwọn alábòójútó àyíká ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù náà bá, wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí látinú Bíbélì. A mọ̀ pé Baba wa ọ̀run Jèhófà ń pèsè ìtùnú fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ń ṣọ̀fọ̀ nítorí àjàlù yìí.—Sáàmù 34:18.