Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àkúnya omi gbé àwọn ọkọ̀ lọ níwájú ilé ìdílé Ẹlẹ́rìí kan ní Harlingen, ìpínlẹ̀ Texas

JULY 10, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìjì Líle àti Àkúnya Omi Ṣọṣẹ́ Ní Gúúsù Ìpínlẹ̀ Texas

Ìjì Líle àti Àkúnya Omi Ṣọṣẹ́ Ní Gúúsù Ìpínlẹ̀ Texas

Ní June 24, 2019, ìjì líle àti òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá ṣọṣẹ́ gan-an ní gúúsù Texas. Ìròyìn fi hàn pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ilé ni ọ̀gbàrá òjò náà bà jẹ́, ó sì ju ọgọ́rùn-ún èèyàn tí wọ́n kó kúrò lágbègbè náà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí akéde kankan tó fara pa nibi ìjì náà, àmọ́ àkéde mẹ́tàdínláàádọ́ta (47) ni ò nílé mọ́ rárá. Yàtọ̀ síyẹn, ìjì náà ba ilé àwọn ará márùndínláàádọ́rin (65) jẹ́, ó sì tún bá ilé kan tá a kọ́ mọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan jẹ́.

Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará tí àjálù náà bá. Bákan náà, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ti ń ṣètò ilé, oúnjẹ, omi àti aṣọ fáwọn ará. Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ ń lọ lórí àtúnṣe àwọn ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́.

A ò ní fi àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní gúúsù Texas sílẹ̀, inú wa dùn pé Jèhófà ni wọ́n gbára lé, ó sì dájú pé á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da àjálù yìí.​—Àìsáyà 26:3, 4.