OCTOBER 19, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ìjì Líle Delta Ṣọṣẹ́ ní Louisiana
Ibi tó ti ṣẹlẹ̀
Louisiana àti Texas
Àjálù
Ìjì líle yìí jà dé Louisiana ní October 9, 2020, ó sì ṣọṣẹ́ gan-an láwọn ibi tí ìjì líle Laura ti jà tẹ́lẹ̀
Ní gbogbo àsìkò tí ìjì náà fi ń jà, òjò àti afẹ́fẹ́ líle pọ̀ débi pé ó fa omíyalé, ìyẹn sì mú kí iná ìjọba lọ láwọn ibi tó pọ̀
Ìpalára tó ṣe fáwọn ará wa
Akéde ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́tàlélọ́gọ́rin (1,583) ló lé kúrò nílé
Àwọn ohun tó bà jẹ́
Ilé ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́rìndínlógún (216) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rìndínlógún (16) ló bà jẹ́ díẹ̀
Ilé méje bà jẹ́ gan-an
Ilé mẹ́ta bà jẹ́ kọjá àtúnṣe
Ètò ìrànwọ́
Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ń pèsè àwọn nǹkan táwọn ará nílò, bí oúnjẹ, omi, ilé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà yìí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù tí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì yàn nígbà ìjì líle Laura. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará wa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe, kí wọ́n lè tẹ̀ lé òfin táwọn elétò ààbò ṣe nípa àrùn Corona (COVID-19)
Àwọn alàgbà túbọ̀ ń sapá láti máa fún àwọn ará níṣìírí. Alàgbà kan sọ ohun tó kíyè sí nígbà tó ṣèbẹ̀wò sáwọn ará, ó ní: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo rí i bí Jèhófà ṣe ń fún àwọn ará yìí lókun. Ó dájú pé Jèhófà ń fún wọn ní ‘agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.’”—2 Kọ́ríńtì 4:7.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń bá a lọ láti jẹ́ “ibi ààbò” fáwọn ará wa ọ̀wọ́n tí àjálù dé bá yìí, ó sì ń “dáàbò bò wọ́n.”—Àìsáyà 4:6.