OCTOBER 2, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ìjì Líle Fa Àkúnya Omi ní Gúúsù Ìlà-Oòrùn Ìpínlẹ̀ Texas
Ní ọ̀sẹ̀ September 16, 2019, ìjì líle Imelda jà ní gúúsù ìlà-oòrùn Texas, ó sì rọ òjò tó fa àkúnya omi, omi náà kún débi pé á fẹ́rẹ̀ẹ́ mu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ dókè. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà pé, ìjì líle yìí ló lágbára jù lọ nínú gbogbo ìjì tó ti ń jà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn tí ìjì náà jà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọkọ̀ làwọn èèyàn pa tì sójú títì àti láwọn ọ̀nà àdúgbò. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló fi ilé wọn sílẹ̀.
Iye àwọn ará wa tó ń gbé lágbègbè tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ ni 29,649, ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sì sọ pé kò sẹ́ni tó fara pa, kò sì sẹ́ni tó kú nínú wọn. Àmọ́, àwọn akéde mérìnléláàádọ́fà (114) ni àjálù náà mú kí wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ilé àwọn ará wa tó jẹ́ márùndínláàádọ́jọ (145) ló bà jẹ́. Ìjì náà sì tún ba Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́wàá jẹ́.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù, ìgbìmọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà, kí wọ́n lè mọ bí ìjì náà ṣe ṣọṣẹ́ tó, kí wọ́n sì lè pèsè ìrànwọ́. A mọ̀ pé Jèhófà máa ti àwọn ará wa lẹ́yìn, torí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ “ga dé ọ̀run.”—Sáàmù 36:5.