AUGUST 6, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ìjì Líle Hurricane Hanna Ṣọṣẹ́ ní Ìlú Texas
Ibi tó ti ṣẹlẹ̀
Texas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
Àjálù
Ìjì líle náà jà ní July 25, 2020, ó sì ru omi òkun sókè gan-an débi pé omi ya wọlé àwọn èèyàn
Ìjì lílé yìí ni àkọ́kọ́ irú ẹ̀ lọ́dún yìí nínú àwọn ìjì tó máa ń gba òkun Àtìláńtíìkì wá
Ìpalára tó ṣe fáwọn ará wa
Àwọn arákùnrin méjì fara pa díẹ̀
Àwọn akéde ọgọ́rùn kan àti mẹ́tàléláàádọ́rùn (193) ló ní láti sá filé wọn sílẹ̀ fúngbà díẹ̀
Àwọn ohun tó bà jẹ́
Ilé ọgọ́rùn mẹ́ta àti mẹ́tàdínláàádọ́ta (347) ti àwọn ará wa ló bà jẹ́ níwọ̀nba
Ilé mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) ló sì bà jẹ́ gan-an
Ètò ìrànwọ́
Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ tó wà lágbègbè tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ ń ṣètò tó yẹ kí wọ́n lè pèsè ìrànlọ́wọ́ nípa tara fáwọn ará wa, kí wọ́n sì ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú
Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” ń tọ́jú àwọn ará wa ní ìlú Texas lásìkò tí nǹkan ò rọgbọ yìí.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.