Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 24, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìjì Líle Hurricane Sally Jà Láwọn Apá Ibì Kan Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ìjì Líle Hurricane Sally Jà Láwọn Apá Ibì Kan Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ibi tó ti ṣẹlẹ̀

Alabama, Florida, and Mississippi

Àjálù

  • Ní September 16, 2020 ìjì kan já dé ìlú Alabama. ìjì náà mú kí òjò rọ̀ gan-an fún wákàtí mélòó kan, ó sì fa omíyalé gidi gan-an

  • Àwọn afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ nígbà tí ìjì náà jà ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́, ó sì mú iná mànàmáná lọ láwọn ibi tó pọ̀

Ìpalára tó ṣe fáwọn ará wa

  • Àwọn ará tó tó igba ó lé lógójì (240) ló ní láti sá fi ilé wọn sílẹ̀

  • Akéde kan fara pa díẹ̀

Àwọn ohun tó bàjẹ́

  • Ilé ọgọ́rùn kan àti ogójì ó lé mẹ́ta (143) bàjẹ́ díẹ̀, pẹ̀lú Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kànlá

  • Ilé méjìlá àti Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bàjẹ́ gan-an

Ètò ìrànwọ́

  • Àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù méjì, àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ ń ṣètò láti fi Ìwé Mímọ́ tu àwọn ará wa nínú, wọ́n sì tún ń pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Bí wọ́ ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn òfin tó ń bá àrùn Corona yìí rìn

Akéde kan sọ pé lẹ́yìn tí ìjì yẹn parí, ṣe lọkàn òun ò balẹ̀ rárá, ó sì rẹ òun gan-an. Lẹ́yìn táwọn ará ìjọ tètè ràn án lọ́wọ́, inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì sọ pé, “Ìfẹ́ táwọn ará fi hàn sí mi àti bí wọ́n ṣe ràn mí lọ́wọ́ ló jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀.”​—1 Jòhánù 3:18.