NOVEMBER 6, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ìjì Líle Hurricane Zeta Jà ní Ìlà Oòrùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
Ibi tó ti ṣẹlẹ̀
Ìlà Oòrùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
Àjálù
Ìjì tó ń yára jà yìí dé Louisiana ní October 28, 2020. Lẹ́yìn ìyẹn ó rọlẹ̀ díẹ̀, àmọ́ ó ṣọṣẹ́ láwọn apá ibòmíì ní ìlà oòrùn Amẹ́ríkà
Ìjì náà kọ lu àwọn etíkun tó wà níbẹ̀, ó ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ títí kan iná mànàmáná
Ìpalára tó ṣe fáwọn ará wa
Àwọn ará ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́rìnlélógún (324) ló pàdánù ilé wọn tàbí tí wọ́n ní láti fi ilé wọn sílẹ̀
Akéde kan ṣèṣe
Àwọn ohun tó bà jẹ́
Ilé àwọn ará ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mọ́kànléláàádọ́rùn-ún (291) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rìnlá (14) ló bà jẹ́ díẹ̀
Ilé àwọn ará mẹ́jọ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta ló bà jẹ́ gan-an
Ilé kan wó pátápátá
Ètò ìrànwọ́
Àwọn alàgbà tó wà lágbègbè náà àtàwọn alábòójútó àyíká ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn tí àjálù náà bá, wọ́n sì ń pèsè ohun tí wọ́n nílò. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù tí ètò Ọlọ́run lò láti pèsè ohun táwọn ará nílò nígbà àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 yìí àti nígbà tí ìjì líle tí wọ́n pè ní Hurricane Laura jà lágbègbè yẹn náà ló pèsè ohun táwọn ará wa nílò níbẹ̀. Wọ́n sì ń pa gbogbo òfin ìjọba nípa àrùn COVID-19 mọ́.
Inú wa ò dùn rárá nígbà tá a gbọ́ ọṣẹ́ tí àjálù yìí ti ṣe fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Àmọ́ ìrànlọ́wọ́ táwọn ará yìí rí gbà jẹ́ kó ṣe kedere pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni Jèhófà ní fáwọn èèyàn rẹ̀.—Sáàmù 89:1.