Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 14, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìjì Líle Isaias Ṣọṣẹ́ Gan-an ní Apá Ìlà Oòrùn Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ìjì Líle Isaias Ṣọṣẹ́ Gan-an ní Apá Ìlà Oòrùn Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ibi tó ti ṣẹlẹ̀

Apá Ìlà Oòrùn Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Àjálù

  • Ìjì líle Isaias dé North Carolina ní August 3, 2020

  • Ìjì náà fẹ́ atẹ́gùn líle bó ṣe ń jà lọ sí etíkun tó wà nílà oòrùn, ó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́, kódà, ó ba iná mànàmáná jẹ́

Ìpalára tó ṣe fáwọn ará wa

  • Arábìnrin wa kan fara pa

  • Ìdílé méjìlá (12) ni ìjì náà mú kó kúrò nílé

Àwọn ohun tó bà jẹ́

  • Márùndínlọ́gọ́ta (55) ni ilé àwọn ará wa tó bà jẹ́ díẹ̀

  • Ilé márùn-ún bà jẹ́ gan-an

  • Ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ló bà jẹ́

  • Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún bà jẹ́ díẹ̀

Ètò ìrànwọ́

  • Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ làwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ tó wà lágbègbè náà ti dìde ìrànwọ́ fáwọn ará wa tọ́rọ̀ kan, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà lórí bá a ṣe lè dènà àrùn corona

Inú wa dùn pé Jèhófà ò fi àwọn ará wa tó wà níbi tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ sílẹ̀. À ń fayọ̀ retí ìgbà tí gbogbo èèyàn máa bọ́ lọ́wọ́ “ìbẹ̀rù àjálù.”​—Òwe 1:33.