Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 14, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìjì Líle Jà ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà

Ìjì Líle Jà ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà

Ní Sunday March 3, 2019, ìjì tó le gan-an jà láwọn apá ibì kan ní ìpínlẹ̀ Alabama, Florida àti Georgia, ó gbẹ̀mí èèyàn mẹ́tàlélógún (23), ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì fara pa.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Amẹ́ríkà sọ pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó kú. Àmọ́ arábìnrin wa kan fara pa nígbà tí ìjì líle ba ilé rẹ̀ jẹ́ pátápátá ní ìlú Fort Valley, ìpínlẹ̀ Georgia. Wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀ nílé ìwòsàn kan tó wà nítòsí. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ pé ilé mẹ́fà àwọn ará wa ni ìjì náà bà jẹ́, ó sì wó ilé mẹ́rin míì pátápátá. Àwọn alábòójútó àyíká tó wà lágbègbè náà ń ṣètò báwọn ará ṣe ń rí oúnjẹ, ibi tí wọ́n á gbé àti aṣọ, àwọn alàgbà sì ń fi Bíbélì fún wọn níṣìírí.

Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa tí àjálù yìí kàn rí ìtùnú nínú ẹṣin ọdún wa ti 2019 tó sọ pé, “Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.”—Aísáyà 41:10.