Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 22, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Barry Gbo Gúúsù Amẹ́ríkà Jìgìjìgì

Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Barry Gbo Gúúsù Amẹ́ríkà Jìgìjìgì

Ní Saturday, July 13, 2019, ìjì líle kan rọ́ lu ìlú Louisiana, kó tó di pé ọwọ́ wà rọlẹ̀ díẹ̀ tí wọ́n fi wá ń pè é ní Barry. Ìjì líle yìí ba nǹkan jẹ́, ó fa àkúnya omi, ó sì jẹ́ kí iná mànàmáná lọ ní ibi púpọ̀ yí ká ìpínlẹ̀ Alabama, Louisiana, àti Mississippi.

Bí o tì lẹ́ jẹ́ pé kò sí akéde kankan tó fara pa tàbí kú nínú ìjì náà, àwọn mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123) ni wọ́n di aláìnílé lórí. Láfikún, ìjì líle náà ba ilé mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún (97) tó jẹ́ ti àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa jẹ́, pẹ̀lú Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún.

Àwọn alábòójútó àyíká àti àwọn alàgbà ìjọ ń lọ bẹ àwọn tọ́rọ̀ náà kàn wò kí wọ́n lè fún wọn níṣìírí. Bákan náà làwọn akéde láti àwọn ìjọ tó wà nítòsí ń pèsè omi, oúnjẹ àti ibùgbé níbi tí wọ́n ti nílò wọn. Wọ́n ti ń ṣètò bí wọ́n á ṣe tún àwọn ilé tó nílò àtúnṣe ṣe.

Àá máa fi àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa ní Gúúsù Amẹ́ríkà tí ìjì líle Barry ṣe lọ́ṣẹ́ sínú àdúrà wa, àá sì máa tì wọ́n lẹ́yìn.—Òwe 18:10.