Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 5, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Dorian Ṣọṣẹ́ Lórílẹ̀-èdè Bahamas

Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Dorian Ṣọṣẹ́ Lórílẹ̀-èdè Bahamas

Ìjì líle tó ń jẹ́ Dorian ni ìjì tó lágbára jùlọ tó tíì jà lórí Òkun Àtìláńtíìkì. Erékùṣù Abaco lápá àríwá Bahamas ló ti wáyé láàárọ̀ Sunday September 1, 2019. Ohun tó mú kí ìjì lílé Dorian burú gan-an ni pé, ìjì náà kìí sáré, ó máa ń fẹ́ atẹ́gùn tó le, àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò sì máa ń rọ̀. Ìjì náà fẹ́ lọ sí erékùṣù Leewards Islands lórílẹ̀-èdè Puerto Rico àti erékùṣù Virgin Islands, àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣọṣẹ́ púpọ̀ níbẹ̀.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń kó ìsọfúnni jọ nípa bí ìjì líle náà ṣe ṣèpalára fáwọn ará wa àtàwọn dúkìá ètò Ọlọ́run. Ìròyìn tó tó wa létí báyìí ni pé kò sí akéde kankan tó fara pa nínú àwọn akéde mẹ́rìndínláàádọ́ta (46) tó wà ní ìjọ méjì tó wà ní erékùṣù Great Abaco Island. Àmọ́, ìjì náà ti ba Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ṣoṣo tó wà ní erékùṣù náà jẹ́.

Ìjọ mẹ́rin ló wà ní erékùṣù Grand Bahama Island, wọ́n sì ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (364) akéde. Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ ni pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó tó igba ó dín mẹ́rin (196) ló sá fi ilé wọ́n sílẹ̀, ilé méjìlélógún (22) ló bà jẹ́ díẹ̀. Ilé mẹ́ta ló sì bà jẹ́ kọjá àtúnṣe.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti fún àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà tó wà níbi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ ní ìtọ́ni kí ìjì náà tó wáyé. Ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ fáwọn ará pé kí wọ́n kó lọ sí olú ìlú Nassau tàbí agbègbè míì tí kò léwu.

Gbogbo ìgbà là ń gbàdúrà fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà níbi tí ìjì líle yìí ti ṣọṣẹ́. A mọ̀ pé Jèhófà ń rí ìyà tó ń jẹ wọ́n, ó sì máa fún wọn lókun tá á jẹ́ kí wọ́n lè fara da àkókò wàhálà yìí.​—Sáàmù 46:​1, 2.