Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilẹ̀ tó lanu lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé

JULY 15, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Ṣọṣẹ́ Ní Gúúsù California

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Ṣọṣẹ́ Ní Gúúsù California

Láti July 4, 2019, àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára wáyé ní Gúúsù California ní agbègbè aṣálẹ̀ Mojave. Ọ̀kan nínú àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ náà lágbára tó 7.1 lórí ìwọ̀n, wọ́n sì gbà pé ó wà lára àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó tíì lágbára jù lọ ní agbègbè yìí láti ogún (20) ọdún sẹ́yìn.

Àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ náà wáyé nítòsí ìlú ńlá Ridgecrest níbi tí àwọn akéde igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (215) ń gbé. A dúpẹ́ pé kò sí ẹnì kankan nínú wọn tó ṣèṣe gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akéde mẹ́ta fara pa díẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìsọfúnni tí a gbà fi hàn pé àwọn akéde méje ló di aláìnílé mọ́. Bákan náà, ilé méje tó jẹ́ tàwọn ará wa bà jẹ́ gan-an, tí márùndínlógójì (35) sì bà jẹ́ díẹ̀. Ní àfikún, Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì ló bà jẹ́ díẹ̀.

Àwọn alábòjútó àyíká méjì ló ń bojú tó ètò ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá ní agbègbè náà. Àwọn alábòjútó àyíká yìí àti àwọn alàgbà tún ń ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábínrin tí àjálù náà bá.

Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fún àwọn ará wa lọ́gbọ́n tí wọ́n nílò láti kojú àwọn àjálù bí èyí.​—Òwe 2:6-8.