FEBRUARY 13, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ìpàtẹ Àwọn Nǹkan Ìṣẹ̀ǹbáyé Ti Wà Báyìí ní Oríléeṣẹ́ Wa Lédè Adití
Bẹ̀rẹ̀ láti January 2019, ó ti ṣeé ṣe fáwọn tó gbọ́ Èdè Adití ti Amẹ́ríkà (ASL) láti túbọ̀ gbádùn ìbẹ̀wò wọn sí oríléeṣẹ́ wa. Ìdí ni pé ní báyìí, a ti mú kí ìpàtẹ tá a kó àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé sí wà lédè wọn. Arákùnrin Enrique Ford, tó jẹ́ alábòójútó Ẹ̀ka Àwọn Nǹkan Ìṣẹ̀ǹbáyé sọ pé: “Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni ẹ̀ka ìtúmọ̀ èdè àti ti kọ̀ǹpútà ṣe láti mú káwọn ará wa lóye àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé yìí ní Èdè Adití ti Amẹ́ríkà (ASL)! Torí náà, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ adití tàbí tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́rọ̀ tí wọ́n máa ń ṣèbẹ̀wò síbi ìpàtẹ wa máa gbádùn ẹ̀ dọ́ba báyìí. Á mú kí wọ́n túbọ̀ mọyì ohun tí wọ́n rí, á wú wọn lórí, á sì túbọ̀ kọ́ wọ́n lẹ́kọ̀ọ́ gan-an.”
Arábìnrin Ana Barrios, tó jẹ́ adití tó sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé nílùú New York, wà lára àwọn tó kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò síbi ìpàtẹ yìí. Ẹ gbọ́ ohun tó sọ: “Nígbà tí mò ń wo àlàyé nípa àtẹ náà lédè adití lórí ẹ̀rọ tí wọ́n gbé fún mi, orí mi wú! Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí mo máa wá síbí rèé, léraléra ni mo sì ti rí àwọn nǹkan tí wọ́n pàtẹ, síbẹ̀ ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ohun tí mo rí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì yé mi dáadáa ju ìgbà tí mo kàn ka èdè òyìnbó tí wọ́n fi ṣàlàyé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ àlàyé náà lédè mi làwọn nǹkan wá túbọ̀ ṣe kedere sí mi. Bí àpẹẹrẹ, mo wá lóye ohun tí orúkọ Jèhófà dúró fún, àṣé mi ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lóye ẹ̀ tẹ́lẹ̀! Yàtọ̀ síyẹn, ìpàtẹ yẹn jẹ́ kí n túbọ̀ lóye àwọn ànímọ́ Jèhófà, àlàyé yẹn wọ̀ mí lọ́kàn débi pé ṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú!”
June 2017 niṣẹ́ títúmọ̀ àti ṣíṣètò bẹ̀rẹ̀ lórí ìpàtẹ àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé ní Èdè Adití ti Amẹ́ríkà. Mẹ́tàlélógún (23) làwọn arákùnrin àti arábìnrin tó kópa nínu rẹ̀, adití ni mẹ́fà lára wọn, mẹ́fà míì sì láwọn òbí tó jẹ́ adití. Gbogbo wọn ló lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ títúmọ̀ àwọn àlàyé yẹn sí ASL, wọ́n sì tún kópa nínú àwọn fídíò náà. Fídíò tí wọ́n ṣe lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900), wọ́n sì gùn tó nǹkan bíi wákàtí mẹ́sàn-án, kó lè bá àlàyé tá a ti gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ mu. Ilé ìgbohùnsílẹ̀ mẹ́ta tó wà fún èdè adití la ti ṣe iṣẹ́ náà: Ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ Èdè Adití (ASL) ní Fort Lauderdale, ìpínlẹ̀ Florida; èyí tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní Wallkill, ìpínlẹ̀ New York; àtèyí tó wà ní oríléeṣẹ́ wa ní Warwick, ìpínlẹ̀ New York. Kó lè dá wa lójú pé kò sí tàbí-ṣùgbọ́n kankan nínú iṣẹ́ náà, a pe àwọn arákùnrin àti arábìnrin mélòó kan tí wọ́n jẹ́ adití, tọ́jọ́ orí wọn sì yàtọ̀ síra pé kí wọ́n bá wa fojú ṣùnnùkùn wò ó. A ṣiṣẹ́ lórí àwọn àkíyèsí wọn kó tó di pé a gbé e jáde níkẹyìn.
Ẹ̀ka Ìṣẹ̀ǹbáyé ra ẹ̀rọ ìgbàlódé alágbèéká mélòó kan tó lè jẹ́ káwọn tó ń sọ èdè adití (ASL) lóye àwọn nǹkan tí wọ́n ń rí bí wọ́n ṣe ń rìn yíká tí wọ́n sì ń fojú lóúnjẹ. Àlàyé kan náà táwọn tó ti nǹkan bọ etí ń gbọ́ nípa ìpàtẹ Warwick yìí làwọn náà ń wò lórí ẹ̀rọ tí wọ́n mú dání. Yàtọ̀ sáwọn ẹ̀rọ téèyàn lè mú dání, Ẹ̀ka Ìṣẹ̀ǹbáyé tún ṣètò ohun tá a lè pè ní tẹlifíṣọ̀n gàdàgbà mẹ́rìnlá míì tó ń ṣàgbéyọ àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé náà, tó sì ń ṣàlàyé wọn lédè ASL.
Mark Sanderson, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Kí nìdí tá a fi ṣètò ìpàtẹ àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé yìí? A fẹ́ kó fún gbogbo àwọn tó ń ṣèbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́ wa níṣìírí, kó sì fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. Inú wa dùn pé èdè mẹ́rìnlá (14) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la fi ṣàlàyé onírúurú nǹkan tó wà níbi ìpàtẹ yìí, títí kan Èdè Adití ti Amẹ́ríkà (ASL). Torí náà, ó dùn mọ́ wa pé àwọn ará wa tó jẹ́ adití àtàwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́rọ̀, títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ló máa jàǹfààní.”
Tá a bá ṣírò ẹ̀, ó lè ní ìlàjì mílíọ̀nù èèyàn tó ti wá ṣèbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́ wa ní Warwick. A ké sí ẹ̀yin ará wa níbi gbogbo láyé pé kẹ́ ẹ wá síbi, kẹ́ ẹ sì fojú ara yín rí àwọn nǹkan tá a pàtẹ síbi ìṣẹ̀ǹbáyé yìí. Ẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀, á jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ mọyì àwọn ohun ribiribi táwa èèyàn Jèhófà ti gbé ṣe àtohun tó ti wáyé nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò sí àní-àní, gbogbo àwọn tó ti wá síbí lo pinnu pé títí láé làwọn á máa “gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.”—Sáàmù 78:7.
Arákùnrin kan ń ṣàtúnyẹ̀wò ọ̀kan lára àwọn fídíò tá a ṣe lédè adití nínú ilé ìgbohùnsílẹ̀ kan ní oríléeṣẹ́ wa ní Warwick, New York. Ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ká lè rí àrídájú ká tó ṣí ibẹ̀ sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti máa ṣèbẹ̀wò.
Àwọn ọmọdé mẹ́ta yìí ń gbọ́rọ̀, àmọ́ adití làwọn òbí wọn. Wọ́n ń wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, tó jẹ́ àtẹ́tísí tá a ṣe lọ́dún 1977, àmọ́ tá a túmọ̀ sí èdè adití (ASL). Àkòrí àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà lédè Gẹ̀ẹ́sì ni “Jehovah’s Name to Be Declared in All the Earth.”
Àwọn arákùnrin àti arábìnrin yìí ń rìn yí ká ibi tá a pàtẹ àwọn Bíbélì sí. Àtẹ náà la pè ní “The Bible and the Divine Name,” ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ẹ̀rọ ìgbàlódé tó ń ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń rí.
Àwọn tó ṣèbẹ̀wò ń wo fídíò tá a ṣe lédè adití lójú tẹlifíṣọ̀n gàdàgbà níbi àtẹ tá a pè ní “A People for Jehovah’s Name.”
Àwùjọ yìí ń rìn yí ká, wọ́n ń wo onírúurú fọ́tò bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) táá fi pilẹ̀ àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá ìyẹn, “Photo-Drama of Creation.” Ẹ̀rọ ìgbàlódé tó wà lọ́wọ́ wọn ń ṣàlàyé àwọn fọ́tò náà lédè adití.