Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 13, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìròyìn Iṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá A Ṣe Nígbà Tí Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Dorian

A Lo Ọkọ̀ Òfúrufú àti Ọkọ̀ Ojú Omi Láti Pèsè Ìrànwọ́ Náà

Ìròyìn Iṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá A Ṣe Nígbà Tí Ìjì Líle Tó Ń Jẹ́ Dorian

Ìjì líle kan tó ń jẹ́ Dorian ṣọṣẹ́ ní erékùṣù Bahamas ní September 1 sí September 3, 2019. Kó tó di pé ìjì náà bẹ̀rẹ̀ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò ìrànwọ́ láti ìpínlẹ̀ Florida, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Gbàrà tá a mọ̀ pé àwọn ará lè lọ síbẹ̀ láìséwu la ti kàn sáwọn ará tó ní ọkọ̀ ojú omi àtàwọn tó ní ọkọ̀ òfúrufú pé kí wọ́n wá ṣèrànwọ́. Kódà, wọ́n wà lára àwọn tó kọ́kọ́ dé erékùṣù náà láti ṣèrànwọ́.

Ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ìgbà làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mẹ́tàlá (13) fi pàrà ibẹ̀ pẹ̀lú ọkọ̀ òfúrufú, tí wọ́n ń lọ káàkiri ibi táwọn ará wà kí wọ́n lè kó ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Ẹrù tí wọ́n kó lọ wúwo tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àpò ìrẹsì, wọ́n sì kó àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje (700) lọ síbẹ̀ láti pèsè ìrànwọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọkọ̀ ojú omi mẹ́tàlá (13) tó jẹ́ tàwọn ará kó ẹrù tó fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àpò ìrẹsì. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó máa ń gbà wákàtí méjìlá láti wa ọkọ̀ láti Bahamas lọ sí Florida àti láti pa dà.

Ọ̀gbẹ́ni Jose Cabrera tó jẹ́ olùdarí ibùdókọ̀ òfúrufú ní Palm Beach International Airport ní Florida sọ pé: “Gbàrà tí ìjì líle náà rọlẹ̀ ni ọkọ̀ òfúrufú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé àwọn ohun èlò ìrànwọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra lọ sí Bahamas. Àpẹẹrẹ àtàtà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi lélẹ̀ yìí ò láfiwé, ìfẹ́ gidi ni wọ́n fi hàn.”

Arákùnrin Glenn Sanders tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti wa ọkọ̀ òfúrufú sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí ọ̀pọ̀ nínú wa máa lo ohun tá a mọ̀ ọ́n ṣe láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Inú wa dùn pé a jẹ́ ẹ̀yà ara kan tó ń mú ìtura bá ẹ̀yà ara míì tó ń jìyà.”​—⁠1 Kọ́ríńtì 12:⁠26.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fojú bù ú pé iṣẹ́ ìrànwọ́ yìí máa ná wọn ní owó tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgbọ̀n mílíọ̀nù owó náìra (ní ti owó dọ́là, ó jẹ́ $1,750,000), iṣẹ́ náà sì máa parí ní May 1, 2020.

 

À ń kó àwọn ohun èlò ìrànwọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi ní Florida, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìgbà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) làwọn ará wa rin ìrìn àjò pẹ̀lú ọkọ̀ ojú omi lọ sí Bahamas

Àwòrán àkúnya omi tó ṣẹlẹ̀ ní pápákọ̀ òfúrufú tó wà ní Great Abaco ní Bahamas

Àwòrán tí wọ́n yà láti inú ọkọ̀ òfúrufú