Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní ọ́fíìsì ìlú Virginia Beach

JUNE 4, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Fara Gbọta Nílùú Virginia Beach Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Fara Gbọta Nílùú Virginia Beach Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Ní May 31, 2019, ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í ròjọ̀ ọta ìbọn lu àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì ìlú Virginia Beach, ìpínlẹ̀ Virginia, lórílẹ̀-èdè United States. Èèyàn méjìlá ló kú, àwọn mẹ́rin sì fara pa.

Ìròyìn tá a gbọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Amẹ́ríkà fi hàn pé, ó ṣeni láàánú pé arábìnrin wa kan tó ń jẹ́, LaQuita Brown, wà lára àwọn tó kù nínú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí. Ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì (39) ni Arábìnrin Brown, aṣáájú-ọ̀nà sì ni nínú Ìjọ Seaview tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé nílùú Norfolk, ìpínlẹ̀ Virginia. Arábìnrin yìí máa ń yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣisẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ. Àwọn alàgbà tó wà lágbègbè náà àti alábòójútó àyílká wọn ń fún tẹbítọ̀rẹ́ Arábìnrin Brown níṣìírí, wọ́n sì ń tù wọ́n nínú.

Ikú arábìnrin yìí dùn wá gan-an. À ń retí àsìkò tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí ò ní wáyé mọ́, tí “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà” á sì wá káàkiri ayé.—Sáàmù 37:10, 11.