Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 19, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ẹnì Kan Yìnbọn ní Ilé Ìwé Kan ní California, Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Ẹnì Kan Yìnbọn ní Ilé Ìwé Kan ní California, Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Ní November 14, 2019, ọmọ ilé ìwé kan dàbọn bolẹ̀ láàárín àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ girama tó wà nílùú Santa Clarita, ní California. Ọmọ náà pa ọmọ ilé ìwé méjì, ó sì ṣe àwọn mẹ́ta léṣe, kó tó wá pa ara ẹ̀.

Ó bani nínú jẹ́ pé Dominic Blackwell, ọmọ arábìnrin wa kan wà lára àwọn ọmọ ilé ìwé tó yìnbọn pa. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) ni, ó sì máa ń lọ sí ìpàdé déédéé pẹ̀lú ìyá rẹ̀ tó ń jẹ́ Nancy Blackwell. Bàbá, ìyá àti àbúrò mẹ́ta ni Dominic fi sílẹ̀. Àwọn alàgbà ń pèsè ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́ fún ìdílé yìí àtàwọn ará ìjọ wọn.

Ó bà wá nínú jẹ́ gan-an pé irú àjálù burúkú yìí ṣẹlẹ̀. À ń retí ìgbà tí Ọlọ́run máa ‘nu gbogbo omijé kúrò tí ikú ò ní sí mọ́, tí kò sì ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.’—Ìfihàn 21:4.