Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 17, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Ilé 107 Columbia Heights, Ibi Táwọn Òṣìṣẹ́ Oríléeṣẹ́ Wa Ń Gbé Tẹ́lẹ̀ ní Brooklyn

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Ilé 107 Columbia Heights, Ibi Táwọn Òṣìṣẹ́ Oríléeṣẹ́ Wa Ń Gbé Tẹ́lẹ̀ ní Brooklyn

ÌLÚ NEW YORK—Ní May 9, 2017, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ta ilé 107 Columbia Heights, tó wà ní àdúgbò Brooklyn Heights Historic District nílùú New York. Iléeṣẹ́ kan tó ń bá iléeṣẹ́ Clipper Realty ṣiṣẹ́ ni wọ́n tà á fún. Àtọdún 1960 ni àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń gbé ní ilé yìí.

Àjà mọ́kànlá [11] ni ilé yìí ní, ó sì gbalẹ̀ gan-an, ó gbà tó ilẹ̀ éékà mẹ́ta àtààbọ̀. Ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi táwọn èèyàn máa ń rìn wá gbafẹ́ ní àdúgbò Brooklyn Heights. Àgbàlá ilé náà ní ọgbà tó rẹwà, ó tún ní orísun kan tí omi ti ń tú jáde, wọ́n sì ṣe àgbàlá kan sórí òrùlé rẹ̀ lókè pátápátá téèyàn lè máa wo afárá Brooklyn Bridge, odò East River àti àdúgbò Lower Manhattan látibẹ̀.

Ọgbà tó wà ní àgbàlá ilé 107 Columbia Heights àti orísun omi tó wà níbẹ̀.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wa tuntun nílùú Warwick ní New York sọ pé: “Nígbà yẹn, inú wa máa ń dùn tá a bá rí i táwọn tá a jọ ń gbé ládùúgbò, pàápàá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ìdílé, ń kọjá níbi ilé 107 Columbia Heights yìí, tí wọ́n sì ń sọ pé àwọn fẹ́ràn bó ṣe rẹwà tó, tàbí tí wọ́n bá ń sọ pé àwọn fẹ́ràn orísun tó wà níbẹ̀, tí omi ti ń tú jáde àti ọgbà tó wà ní àgbàlá ilé náà. Ó lé ní àádọ́ta [50] ọdún tá a fi lo ilé yìí, ó sì ti di ibi pàtàkì ní àdúgbò Brooklyn Heights.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000