OCTOBER 1, 2021
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
A Mú Ìwé Ìhìn Rere Mátíù Jáde Lédè Hmong
Ní September 25, 2021, a mú Ìwé Ìhìn Rere Mátíù (The Bible—The Gospel According to Matthew) jáde lórí ẹ̀rọ lédè Hmong. Arákùnrin Geoffrey Jackson, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló mú ìwé náà jáde nínú ìpàdé pàtàkì kan tí wọ́n gbà sílẹ̀. Àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àtààbọ̀ (2,500) ló wo ètò náà kárí ayé.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn tó ń sọ èdè Hmong kárí ayé, ìwé tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde yìí sì ni ìwé àkọ́kọ́ lára Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó wà ní èdè náà. a Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Hmong ló sábà máa ń jọ́sìn àwọn nǹkan tó wà láyìíká wọn torí wọ́n gbà pé gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ làwọn nǹkan yẹn ń rí. Wọ́n tún gbà pé àwọn ẹ̀mí rere àti ẹ̀mí burúkú ló ń darí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti pé àwọn tó ní agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lè tu àwọn ẹ̀mí náà lójú.
Lẹ́yìn ọdún 1970, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Hmong ló sá lọ sí ibùdó àwọn tó ń wá ibi ìsádi ní Thailand. Nígbà tó yá, àwọn kan lára àwọn tó sá lọ síbẹ̀ ṣí lọ sílẹ̀ Yúróòpù àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àmọ́ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n pọ̀ sí jù.
Ní báyìí, apá ibi táwọn tó ń sọ èdè Hmong pọ̀ sí jù lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni California, Minnesota àti Wisconsin. Ọdún 2007 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè Hmong. Lọ́dún 2012, a kọ́ ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè sí Sacramento, ní California.
Ó ju oṣù mẹ́ta tí àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè fi túmọ̀ Ìwé Ìhìn Rere Mátíù. Àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì bá wọn ka ìwé náà kí wọ́n tó gbé e jáde.
Oríṣiríṣi ìṣòro làwọn atúmọ̀ èdè ní nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ ìwé náà. Bí àpẹẹrẹ, láti nǹkan bí ọdún 1950 tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè Hmong, kò sí ìlànà pàtó lórí bí wọ́n ṣe lè kọ ọ́ sílẹ̀.
Ẹ̀yìn ọdún 1980 ni wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ Bíbélì sí èdè Hmong, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè náà ni ò lè rówó rà á. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ohun tó wà nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì yẹn ni ò péye, ìyẹn sì mú kó nira fáwọn èèyàn láti lóye rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọ̀kan lára àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì yẹn, wọ́n yọ Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run kúrò, wọ́n sì fi orúkọ ọ̀kan lára àwọn akọni inú ìtàn Hmong rọ́pò rẹ̀.
Ọ̀kan lára àwọn tó túmọ̀ Bíbélì tuntun yìí sọ pé: “Ní báyìí tá a ti ní Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Hmong, ó máa rọrùn fáwọn olóòótọ́ ọkàn láti rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì wọn, wọ́n á sì lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kéyìí ṣeé ṣe.”
Àwọn tó ń ka ìwé yìí mọyì bí ìtumọ̀ ẹ̀ ṣe péye. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo ka Ìwé Ìhìn Rere Mátíù lédè Hmong. Ṣe ni mò ń bi ara mi pé, ‘Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìwé yìí tó fi di pé mo nírú ìmọ̀lára tí mo ní nígbà tí mo kà á?’ Mo wá rí i pé ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.”
Bá a ṣe mú Ìwé Ìhìn Rere Mátíù jáde lédè Hmong ti túbọ̀ rán wa létí ohun pàtàkì kan nípa Jèhófà Ọlọ́run wa, ìyẹn ni pé kì í ṣe ojúsàájú, ó sì wù ú kí gbogbo àwọn tó ń wá a rí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà lédè tó máa yé wọn dáadáa.—Ìṣe 10:34, 35.
a Kò rọrùn fáwọn tó ń ṣèwádìí láti mọ àròpọ̀ iye àwọn tó ń sọ èdè Hmong lágbàáyé. Wọ́n fojú bù ú pé ohun tó ju mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ èèyàn ló ń sọ èdè Hmong lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Ṣáínà. Àwọn tó ju mílíọ̀nù kan ló wà ní Laos, Thailand, apá àríwá Vietnam àti apá ìlà oòrùn Myanmar. Bákan náà, àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́sàn-án (170,000) ló ń sọ èdè yìí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.