Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún kọ́ ní 1228 Pensacola Street, Honolulu, Hawaii

APRIL 22, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

A Ya Gbọ̀ngàn Ìjọba Àkọ́kọ́ Sí Mímọ́ Lẹ́ẹ̀kan Sí I Lẹ́yìn Ọdún Márùnlélọ́gọ́rin (85)

A Ya Gbọ̀ngàn Ìjọba Àkọ́kọ́ Sí Mímọ́ Lẹ́ẹ̀kan Sí I Lẹ́yìn Ọdún Márùnlélọ́gọ́rin (85)

Ọdún 1935 ni ìṣẹ̀lẹ̀ amọ́kànyọ̀ yìí kọ́kọ́ wáyé. Arákùnrin Joseph F. Rutherford, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ojúlé 1228 ní Pensacola Street, ìlú Honolulu, ìpínlẹ̀ Hawaii. Kò ní yà yín lẹ́nu pé ilé kékeré tí wọ́n kọ́ nígbà yẹn ni ilé ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a kọ́kọ́ pè ní “Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Àtìgbà yẹn làwa èèyàn Jèhófà ti ń pe àwọn ibi tá a máa ń kóra jọ sí láti jọ́sìn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn sì ti lé lọ́gọ́rin (80) ọdún báyìí. Ní báyìí, àwọn ìjọ mẹ́rin ló ń ṣèpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn, èdè márùn-ún ni wọ́n sì fi ń ṣèpàdé níbẹ̀, títí kan èdè Hawaii Pidgin. *

Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn rèé lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ ọ lọ́dún 1935

Ní February 11 sí 15, 2020, ìyẹn kí àrùn COVID-19 tó gbayé kan, lẹ́yìn tá a ti tún Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ yẹn kọ́, àwọn ará wa pe àwọn ará ìlú, àwọn aṣojú ìjọba àtàwọn olùkọ́ láti wá ṣèbẹ̀wò kí wọ́n sì rín yí ká ilé náà. Àwọn ará wa mú àwọn àlejò náà rìn yí ká ilé náà, kí wọ́n lè rí onírúurú fọ́tò àtàwọn àkọ́sílẹ̀ ìtàn nípa ilé náà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arákùnrin tún ṣàlàyé àwọn nǹkan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ṣe lóde òní fún wọn. Nígbà tó di February 16, Arákùnrin David H. Splane tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá fọba lé e pẹ̀lú àsọyé ìyàsímímọ́.

Arábìnrin kan tó wà lára àwọn tó ṣe àwọn ìmúrasílẹ̀ kan kí ètò náà lè kẹ́sẹ járí sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe torí àtiwàásù fáwọn èèyàn náà la ṣe ní kí wọ́n wá ṣèbẹ̀wò, a gbà pé ẹ̀rí ńlá ni ìbẹ̀wò náà jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó ṣeé ṣe kí wọ́n má mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Ètò tá a ṣe pé káwọn èèyàn rìn yí ká Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn mú káwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin túbọ̀ lóye ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn erékùṣù Hawaii, ó sì mú kí wọ́n rí ìmúṣẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sọ pé: “Ní àwọn erékùṣù òkun, wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.”​—Àìsáyà 24:15.

^ ìpínrọ̀ 2 Lásìkò tí àrùn COVID-19 gbòde, orí ẹ̀rọ ayélujára ni gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ń ṣèpàdé dípò kí wọ́n máa kóra jọ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.