SEPTEMBER 18, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ijì Lílé Tó Ń Jẹ́ Dorian Runlé-rùnnà
Ìjì líle tó ń jẹ́ Dorian yìí kọ́kọ́ jà ní àwọn erékùṣù tó wà ní Bahamas, ó sì ba nǹkan jẹ́ níbẹ̀ gan-an. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá rọ́ lọ sí àwọn etíkun tó wà ní ìlà oòrùn Amẹ́ríkà. Ní àárọ̀ Friday, September 6, 2019, ó kọjá ní ìlú Cape Hatteras ní North Carolina, ó sì fa àkúnya omi tó ń ru gùdù, èyí tó ya wọ ilé àti àwọn ilé ìtajà káàkiri. Ní September 7, 2019, ìjì náà fa ẹ̀fúùfù líle gan an nílùú Nova Scotia, ní orílẹ̀ èdè Kánádà.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ròyìn pé lára àwọn akéde tó tó ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlélógójì (1,742) tó wà ní Bahamas, arábìnrin kan ṣoṣo ló kàn fara pa díẹ̀. Ní àsìkò tá a ń kọ ìròyìn yìí, ilé méjìdínláàádọ́ta (48) tó jẹ́ ti àwọn ará wa ni ìjì náà bà jẹ́ nígbà tí ilé mẹ́jọ bàjẹ́ kọjá àtúnṣe.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn akéde tó ń gbé ní erékùṣù Great Abaco ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò pé kí wọ́n kó lọ sí ìlú Nassau, tó jẹ́ olú ìlú Bahamas. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó sì wà níbẹ̀ kí wọn káàbọ̀ tayọ̀tayọ̀ ní pápá ọkọ̀ òfuurufú.
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù àti alábòójútó àyíká tó wà ní agbègbè náà ń ṣètò ìtọ́jú pàjáwìrì, wọ́n sì tún ń ṣètò ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn fún àwọn akéde tí àjálù dé bá. Àwọn arákùnrin láti ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà náà rìnrìn àjò lọ sí agbègbè náà kí wọ́n lè pèsè àwọn ohun tí àwọn ará yìí nílò kí wọ́n sì fi Bíbélì tù wọ́n nínú.
Ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, apá Àríwá àti Gúúsù Carolina ni ìjì náà ti ṣọṣẹ́ jùlọ. Ko sí arákùnrin tàbí arábìnrin kankan tó fara pa nínú àjálù náà, àmọ́ àwọn ará tó tó ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàdínlógójì (737) ló ni láti sa fi ilé wọn sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn ní ìgbìmọ̀ náà ṣètò pé kí wọ́n kó kúrò fúngbà díẹ̀ títí dìgbà tí wọ́n a fì lè pa dà sílé. Bákan náà, àádọ́ta (50) ilé àti gbọ̀ngàn ìjọba méjìlá (12) ló bà jẹ́.
A ò gbọ́ ìròyìn pé ẹnikẹ́ni lára àwọn ará wà ní Kánádà fara pa. Ìjì náà ba àwọn nǹkan díẹ̀ jẹ́ lára ilé àwọn arákùnrin wa kan, bẹ́ẹ̀ ló sì ba iná mànàmáná wọn jẹ́. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ ládùúgbò yẹn ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ará tí àjálù náà dé bá.
A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ń gbọ́ “ẹ̀bẹ̀ [àwọn ará wa] fún ìrànlọ́wọ́,” bí wọ́n ṣe ń gbọ́kàn lé e ní àkókò tí nǹkan lè koko yìí.—Sáàmù 28:6