Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 17, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Jàǹbá Iná Ń Ṣọṣẹ́ ní Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Jàǹbá Iná Ń Ṣọṣẹ́ ní Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ibi tó ti ṣẹlẹ̀

California, Oregon àti Washington

Ohun tó ṣẹlẹ̀

  • Iná tó ń yára ṣọṣẹ́ jó ohun tó ju mílíọ̀nù márùn-ún éékà ilẹ̀ láàárín California sí Washington

  • Èéfín iná yẹn ti ba afẹ́fẹ́ jẹ́

  • Ọ̀kan lára ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn burú gan-an débi pé òun ló tíì ṣọṣẹ́ jù lọ nínú ìtàn California

Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe kan àwọn ará wa

  • Àwọn akéde tó tó 4,546 ló ti fi ilé wọn sílẹ̀

Àwọn nǹkan tó bà jẹ́

  • Ilé mọ́kànlélọ́gọ́ta (61) bà jẹ́ gan-an

  • Ilé mẹ́rìndínlógún (16) nílò àtúnṣe

Bá a ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́

  • Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará tí wọ́n ti fi ilé wọn sílẹ̀. Wọ́n tún rí i pé wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni táwọn elétò ààbò ṣe torí àrùn COVID-19

Àwọn akéde tọ́rọ̀ yìí kàn ti rọ́wọ́ Jèhófà lára wọn, wọ́n sì mọyì bí ètò Ọlọ́run ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin tílé ẹ̀ bàjẹ́ sọ pé àwọn ará wa “múra tán láti pèsè ohun tá a nílò kódà ká tó ronú pé a nílò ẹ̀.”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún àwọn ara wa yìí, síbẹ̀ wọ́n ń rí i pé Jèhófà ò fi àwọn sílẹ̀, ó ń tọ́jú àwọn, ó sì ń fàánú hàn sáwọn.​—Jémíìsì 5:11.