SEPTEMBER 1, 2020
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Jàǹbá Iná Ṣọṣẹ́ Lápá Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
Ibi tó ti ṣẹlẹ̀
Apá àríwá California àti Oregon
Ohun tó ṣẹlẹ̀
Ààrá sán ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá (14,000) ìgbà, àwọn nǹkan míì tún ṣẹlẹ̀ tó mú káwọn ààrá yìí fa iná tó lágbára. Ó le débi pé àwọn agbègbè tó ju ọgọ́rùn-ún méje (700) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló jó. Iná yìí ti jó ilẹ̀ tó ju mílíọ̀nù kan éékà lápá àríwá California àti láwọn apá ibì kan ní Oregon
Èéfín iná tó jó yìí ti ba afẹ́fẹ́ jẹ́ gan-an. Ní August 21, a gbọ́ ìròyìn kan pé afẹ́fẹ́ tó wà ní apá àríwá California ló burú jù lọ láyé
Nígbà táwọn oníròyìn ń fi jàǹbá yìí wé àwọn tó ti ṣẹlẹ̀, wọ́n sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti wáyé rí tó burú gan-an nínú ìtàn California, wọ́n sì sọ pé méjì lára èyí tó ṣẹlẹ̀ báyìí ló wà nípò kejì àti kẹta
Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe kan àwọn ará wa
Àwọn akéde tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mẹ́rìndínlógójì (936) ló ti kúrò nílé
Àwọn nǹkan tó bà jẹ́
Ilé àwọn akéde méjì ló ti bàjẹ́ pátápátá
Bá a ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù, àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran àwọn tọ́rọ̀ kàn lọ́wọ́
Àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin mọrírì báwọn ará ṣe dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro. Arákùnrin kan sọ pé: “Kò sí bí nǹkan náà ṣe lè burú tó, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ètò Ọlọ́run á ti dé láti ràn wá lọ́wọ́. Inú wa dùn gan-an láti wà lára ìdílé yìí.” Bá a ṣe ń ṣètò ìrànwọ́ fáwọn ará wa ti jẹ́ kó dá gbogbo wa lójú pé kò sóhun tó “lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:39.