JUNE 13, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ojú Ọjọ́ Tí Kò Bára Dé Ba Nǹkan Jẹ́ Láwọn Ibì Kan Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
Lóṣù May 2019, ìròyìn fi hàn pé ojò púpọ̀ tó rọ̀ àti ọgọ́rùn márùn-ún (500) ìjì líle tó jà ní Amẹ́ríkà ba nǹkan jẹ́ gan-an.
Ojú ọjọ́ tí kò bára dé yìí kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìpínlẹ̀ Arkansas, Indiana, Mississippi, Missouri, Ohio, Oklahoma, Pennsylvania àti Texas. Kò sí ìkankan lára àwon ará wa tó bá àjálù náà lọ. Àmọ́, mẹ́fà lára wọn fara pa, mẹ́rin nínú wọn sì wà nílé ìwòsàn. Yàtọ̀ síyẹn ilé mẹ́fà àwọn ará wa ló bà jẹ́ pátápátá, ilé méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìlá sì bà jẹ́. Gbogbo èyí mú kí àwọn ará mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) kúrò níbi tí wọ́n ń gbé.
Báwọn ará ṣe ń yẹ àwọn nǹkan tó bà jẹ́ wò, wọ́n ń pèsè oúnjẹ, omi àti ibùgbé fáwọn tọ́rọ̀ náà kàn. Àwọn alàgbà ìjọ àtàwọn alábòójútó àyíká tó wà lágbègbè náà ń fún àwọn ará níṣìírí, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú.
A ò ní ṣíwọ́ ìrànwọ́, a ò sì ní dákẹ́ àdúrà fáwọn ará wa bí wọ́n ṣe ń fara da ìṣòro tí ìjì tó jà ti dá sílẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.