Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 1, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Ilé The Towers, Tó Jẹ́ Ibi Pàtàkì Nínú Ìtàn Wa

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Ilé The Towers, Tó Jẹ́ Ibi Pàtàkì Nínú Ìtàn Wa

NEW YORK—Ní October 31, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ta ilé gbígbé alájà mẹ́rìndínlógún (16) tó wà ní 21 Clark Street, ní àdúgbò Brooklyn Heights Historic District. Ó ti lé ní ogójì (40) ọdún tó ti jẹ́ tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Òtẹ́ẹ̀lì ni wọ́n fi ń ṣe tẹ́lẹ̀, wọ́n kọ́ ọ bíi tàwọn ará Róòmù àtijọ́, a sì ń tọ́jú ilé náà látìgbà yẹn kó má bàa yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe kọ́ ọ.

Leverich Towers Hotel gangan ni wọ́n sọ ilé náà nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kọ́ ọ, wọ́n sì ṣí i lọ́dún 1928. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí wọ́n yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Towers Hotel. Wọ́n ní òun ló gbayì jù nínú àwọn òtẹ́ẹ̀lì tó wà ní Brooklyn nígbà yẹn, àwọn èèyàn pàtàkì-pàtàkì ló sì máa ń lọ síbẹ̀. Àmọ́ nígbà tó fi máa di àárín ọdún 1970 sí 1979, wọ́n ti pa ilé náà tì, wọn ò sì tún un ṣe mọ́.

Ọdún 1975 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ra ilé náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ́kọ́ yá ọ̀pọ̀ yàrá níbẹ̀ káwọn òṣìṣẹ́ oríléeṣẹ́ wọn lè máa gbébẹ̀, torí pé ibi tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ ò gbà wọ́n mọ́. Ẹ̀ẹ̀mejì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàtúnṣe sí ilé náà lẹ́yìn tí wọ́n rà á: 1978 ni ìgbà àkọ́kọ́, 1998 ni ìgbà kejì.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Kì í ṣe ojú ilé kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ lásán làwa tá a gbé ní àdúgbò Brooklyn Heights fi ń wo ilé The Towers, a ò lè gbàgbé ibẹ̀ torí pé ó rẹwà gan-an, ilé tó sì tura ni. Bá a tún ṣe ta ilé míì tó jẹ́ ibi pàtàkì nínú ìtàn wa ní Brooklyn nìyẹn o.”

Lọ́dún 2016, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó oríléeṣẹ́ wa lọ sílùú Warwick, ní New York.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000