Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 6, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Lágbára ní Alaska

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Lágbára ní Alaska

Ní November 30, 2018, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára ṣẹlẹ̀ nítòsí ìlú Anchorage, ìpínlẹ̀ Alaska. Bí tiẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó bá ìmìtìtì ilẹ̀ náà lọ, àwọn oníròyìn sọ pé ó ba àwọn ọ̀nà jẹ́ gan-an.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Amẹ́ríkà ròyìn pé àwọn akéde méje fara pa díẹ̀ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé. Ilé mẹ́rìndínlógún (16) àwọn ará wa àti Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì ló bà jẹ́. Àwọn alábòójútó àyíká ṣètò bí àwọn ìjọ á ṣe máa pèsè oúnjẹ, aṣọ omi àti ilé fún àwọn ará tó nílò wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà tó wà lágbègbè náà ń fi Bíbélì tu gbogbo àwọn tí àjálù náà kàn nínú.

À ń rántí àwọn ará wa tí ìmìtìtì ilẹ̀ yìí kàn nínú àdúrà wa. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa jẹ́ agbára àti ibi ààbò fún àwọn èèyàn rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé e.—Sáàmù 28:8, 9.