DECEMBER 7, 2015
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Àwa Ẹlẹ́rìí Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ta Àwọn Ilé àti Ilẹ̀ Wa Tó Wà ní Brooklyn
ÌLÚ NEW YORK—Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ta àwọn ilé àti ilẹ̀ wa kan nílùú Dumbo àti Brooklyn Heights ní Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York. Wìtìwìtì láwọn èèyàn ń du àti rà á. A fẹ́ ta ilẹ̀ wa kan tó wà ní 85 Jay Street, ilẹ̀ yìí wà lára àwọn ilẹ̀ tá ò tíì kọ́lé sí tó fẹ̀ jù nílùú Brooklyn. A tún fẹ́ ta ilé alájà mẹ́wàá kan tó wà ní 124 Columbia Heights. Bákan náà a tún fẹ́ ta orílé-iṣẹ́ tá à ń lò báyìí, èyí tó wà ní 25/30 Columbia Heights. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la fẹ́ ta àwọn dúkìá yìí, a sì ti ṣètò pé kí Watchtower Real Estate Office bá wa tà á.
Richard Devine, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ nípa ilẹ̀ tó fẹ̀ gan-an tá a sọ pé ó wà ní 85 Jay Street yẹn pé: “Ilẹ̀ yìí fẹ̀ dé àwọn odi ìlú tó wà lágbègbè ìlú Dumbo ó sì wà ní ipò to dáa.”
Ibì kan táwọn èèyàn máa ń ṣeré lọ ní àgbègbè Brooklyn Heights Historic District tọ́pọ̀ èèyàn fẹ́ràn ni ilé alájà mẹ́wàá tó wà ní 124 Columbia Heights wà. Ọ̀gbẹ́ni Devine sọ pé: “Ilé àwòṣífìlà ni. Téèyàn bá wà nínú ilé yìí, á máa rí àwọn ohun tó rẹwà bí afárá Brooklyn, ère tí wọ́n fi ń dá ìlú New York mọ̀, àtàwọn ilé gíga Lower Manhattan.”
Ọjọ́ ti pẹ́ tí oríléeṣẹ́ wa ti wà ní 25/30 Columbia Heights, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé nílùú New York sì ti mọ̀ ọ́n mọ́ àmì Ilé ìṣọ́ àti aago tó wà níbẹ̀. Pẹ̀lú bí ilé yìí ṣe ga tó, to sì fẹ̀ gan-an, síbẹ̀ kò dí èèyàn lọ́wọ́ láti rí afára Brooklyn lọ́ọ̀ọ́kán.
Ọ̀gbẹ́ni Devine tún sọ pé, “Bá a ṣe ń ta àwọn dúkìá yìí, ohun tó kàn ni ká kó lọ sí oríléeṣẹ́ wa tó wà ní Warwick nílùú New York.”
Láti mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ilé àti ilẹ̀ tá a fẹ́ tà yìí, jọ̀ọ́ lọ sórí ìkànnì www.WatchtowerBrooklynRealEstate.com. Tó o bá fẹ́, o lè rí àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àtàwọn fọ́tò gbà látọwọ́ Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde,, tel. +1 718 560 5000