Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 1, 2016
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tún Ìsédò Kan Tó Ti Wà ní Warwick Láti Ọgọ́ta Ọdún Sẹ́yìn Ṣe

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tún Ìsédò Kan Tó Ti Wà ní Warwick Láti Ọgọ́ta Ọdún Sẹ́yìn Ṣe

ÌLÚ NEW YORK—Ní August 2016, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà parí oríléeṣẹ́ wọn tuntun tí wọ́n ń kọ́ sí Warwick, nílùú New York. Wọ́n sì tún ti parí àtúnṣe tí wọ́n ń ṣe sí ìsédò Blue Lake bí wọ́n ṣe ní in lọ́kàn láti ṣe, iléeṣẹ́ SUEZ Water New York Inc. sì ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu àtúnṣe yìí.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí ra ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ kọ́lé sí lọ́dún 2009 tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò láti tún ìsédò Blue Lake tó ti bà jẹ́ gan-an ṣe. Ẹ̀gbẹ́ oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tuntun ni ìsédò náà (tó wà láàárín nínú fọ́tò lókè) wà, òun ló sì sé adágún omi Blue Lake (tí wọ́n tún ń pè ní Sterling Forest Lake) mọ́. Iléeṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Àyíká wá wo ìsédò náà, wọ́n sì rí i pé òótọ́ ni ìsédò náà ń jo omi, àti pé ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣí i tí wọ́n sì fi ń tì í náà ti bà jẹ́. Iléeṣẹ́ ìjọba náà sọ pé bí ìsédò yẹn ṣe dẹnu kọlẹ̀ léwu gan-an torí pé àwọn kan ń gbé ní àdúgbò tí igi pọ̀ sí ní Tuxedo, ibẹ̀ ò jìnnà rárá síbi odò Blue Lake, igba ó dín márùn-ún [195] sì ni ilé tó wà níbẹ̀.

Ẹ̀gbẹ́ ìsédò Blue Lake (tó wà láàárín, lápá ọ̀tún) ni oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà (tó wà nísàlẹ̀, lápá òsì) wà.

Jeffrey Hutchinson, ọ̀gá ọgbà Sterling Forest State Park tẹ́lẹ̀.

Jeffrey Hutchinson, tó jẹ ọ̀gá ọgbà Sterling Forest State Park nígbà yẹn sọ pé: “Ìsédò yẹn ń jo omi lóòótọ́, ọjọ́ tọ́rọ̀ bá sì fi lè yíwọ́ pẹ́nrẹ́n, nǹkan á bà jẹ́ gan-an. Gbogbo ilé àwọn tó ń gbé ní àdúgbò tí igi pọ̀ sí ní Tuxedo, tàbí ká sọ pé èyí tó pọ̀ jù nínú wọn, ló máa pa rẹ́.”

Robert R. Werner, tó jẹ́ alága àwọn onílé ní àdúgbò yẹn ní Tuxedo sọ pé: “Ó dá mi lójú pé ká ní àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò dá sí ọ̀rọ̀ yìí ni, bí ìsédò yìí ò bá ṣe wà nìyẹn, títí nǹkan á fi yíwọ́. Ká ní ìyẹn lọ ṣẹlẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ ohun ìní wa ni ò bá bà jẹ́, ẹ̀mí àwọn èèyàn ò bá sì lọ sí i.”

Ibi táwọn èèyàn ń gbé ní àdúgbò tí igi pọ̀ sí ní Tuxedo (tó wà lókè, lápá òsì) kò jìnnà rárá sí oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà (tó wà nísàlẹ̀, lápá ọ̀tún) àti ìsédò Blue Lake.

Ọ̀gbẹ́ni Hutchinson sọ pé: “Lọ́dún 2011, ìsédò Echo Lake, tó wà níbi tí kò tó àádọ́ta [50] kìlómítà sí odò Blue Lake, dẹnu kọlẹ̀, omi wá ya wọ àwọn ibì kan ní àgbègbè East Village ní Tuxedo, nílùú New York, ó sì ba ibẹ̀ jẹ́ gan-an.” Àwọn ẹnjiníà tó wà lágbègbè náà sọ pé omi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kún ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] àgbá omi ńlá ló ya látinú Odò Ramapo nígbà tí ìsédò Echo Lake dẹnu kọlẹ̀. Adágún omi Echo Lake tóbi gan-an, àmọ́ kò tó ìdá mẹ́jọ omi odò Blue Lake.

Ọdún 1956 ni wọ́n ṣe ìsédò Blue Lake, apá ìlà oòrùn adágún odò náà ló wà, apá méjì ló sì ní nígbà tí wọ́n kọ́ ọ. Àkọ́kọ́ ni ògiri tó sé odò náà, èkejì sì ni ibi tí wọ́n fi kọnkéré ṣe tí omi náà á máa gbà tí wọ́n bá ṣí i. Wọ́n tún ṣe ẹ̀rọ kan sí ìsàlẹ̀ omi náà, tí wọ́n á máa ṣí kí omi náà lè ṣàn gba ibòmíì tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó dédé kún, tó sì fẹ́ ya.

Richard Devine, tó jẹ́ alága Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìkọ́lé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní Warwick sọ pé: “Inú wa dùn pé a rí ìsédò náà tún ṣe, a sì dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ iléeṣẹ́ SUEZ Water pé wọ́n ràn wá lọ́wọ́. A tún ògiri tí wọ́n fi sé odò náà ṣe dáadáa, a gbé ẹ̀rọ míì sínú odò náà, a ṣe ibòmíì yàtọ̀ sí èyí tó wà tẹ́lẹ̀ tómi lè gbà tí wọ́n bá ṣí omi odò náà, a sì tún ibi tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀ pé kí omi máa gbà ṣe kó lè lágbára sí i. Àtúnṣe yìí ti wá jẹ́ kí ìsédò náà rí bí ìjọba ṣe fẹ́ kó rí, ìyẹn ni pé kó wà ní ipò tó dáa kó má bàa séwu.”

Ní ṣókí, Ọ̀gbẹ́ni Hutchinson sọ ojú tó fi wo àwọn Ẹlẹ́rìí lápapọ̀ àti iṣẹ́ tí wọ́n ṣe níbi ìsédò náà, ó ní: “Ọ̀pọ̀ nǹkan rere lẹ̀yin ajẹ́rìí máa ń ṣe fáwọn ará àdúgbò, ẹ sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ tágbára yín bá gbé e. Iṣẹ́ ìkọ́lé yín ló máa ń dáa jù, ẹ kì í sì í ṣe é lọ́nà tó máa pa àyíká lára.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

 

Àwọn òṣìṣẹ́ Watchtower ń yọ ẹ̀rọ tó wà nísàlẹ̀ adágún omi Blue Lake kúrò torí kò ṣiṣẹ́ mọ́. Ẹ̀rọ yẹn ni wọ́n máa ń ṣí kí omi odò náà lè ṣàn lọ síbòmíì tó bá ṣẹlẹ̀ pé omi náà dédé kún ya.

Wọ́n ń gbé asẹ́ ńlá kan sínú odò náà, kí ìdọ̀tí ńláńlá má bàa dí ojú ibi tí omi máa ń gbà jáde tí wọ́n bá ṣí i.

Àwọn òṣìṣẹ́ Watchtower ń ṣe ibi tí omi máa ń ṣàn gbà kó lè fẹ̀ sí i. Tí omi Blue Lake bá ti kún, ibí ló máa ń ṣàn gbà lọ sínú odò kan tó wà ní tòsí.

Àwọn òṣìṣẹ́ Watchtower ń kọ́ ògiri ibi tí omi máa ń ṣàn gbà kó lè fi ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin ga sí i, wọ́n sì ń tún àwọn ibi tó sán lára ògiri náà ṣe.

Yẹ̀pẹ̀ tí ò dáa ni wọ́n fi ṣe àyíká odò náà tẹ́lẹ̀, àmọ́ yẹ̀pẹ̀ lẹ́búlẹ́bú tí wọ́n máa ń lò fún irú iṣẹ́ yìí ni wọ́n ń dà síbẹ̀ báyìí. Yẹ̀pẹ̀ tí wọ́n lò ju èyí tó kún ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] ọkọ̀ yẹ̀pẹ̀ lọ.

Wọ́n ń fi katakata parí iṣẹ́ lórí ibi tí wọ́n da yẹ̀pẹ̀ lẹ́búlẹ́bú náà sí kó lè dán.

Àwọn òṣìṣẹ́ wá da yẹ̀pẹ̀ gidi sórí ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbin koríko sí i kí ilẹ̀ ibẹ̀ má bàa yàtọ̀ sí ti àyíká.