OCTOBER 31, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Fídíò Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ran Àwọn Òbí Lọ́wọ́ Láti Bójú Tó Ìṣòro Ìhalẹ̀mọ́ni, Tó Ń Kó Bá Ìlera Ọmọ
NEW YORK—Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nínú ìwádìí tí ilé ìwòsàn C.S. Mott Children’s Hospital ṣe ní Yunifásítì Michigan lọ́dún 2017 lorí ọ̀rọ̀ ìlera àwọn ọmọ lórílẹ̀-èdè náà, àwọn òbí sọ pé nínú gbogbo ohun tó ń nípa lórí ìlera ọmọ àwọn, àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ náà ló máa ń nípa tó lágbára jù lórí wọn.
Ìkànnì stopbullying.gov, tó wà lábẹ́ àbójútó Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ìlera àti Àbójútó Àwọn Èèyàn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, jẹ́ ká rí ohun tó ṣeé ṣe kó mú kí ọ̀rọ̀ náà ká àwọn òbí lára. Ó ní ìwádìí tó jinlẹ̀ fi hàn pé ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá àwọn ọmọ iléèwé ní Amẹ́ríkà ló sọ pé àwọn kan ti halẹ̀ mọ́ àwọn rí.
David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn ní New York sọ pé: “A mọ̀ pé ipa kékeré kọ́ ló máa ń ní lórí àwọn ọmọ tí wọ́n bá halẹ̀ mọ́ wọn. Torí náà, àwọn àpilẹ̀kọ, ìwé àtàwọn fídíò tó dá lórí béèyàn ṣe lè kojú àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ ọn àtèyí tó dá lórí àwọn ìṣòro míì tí ìdílé ń kojú wà lára ohun tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún márùn-ún báyìí tí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìdílé kárí ayé ti rí i pé fidíò bèbí kan tí kò gùn tá a ṣe jáde ti ran àwọn lọ́wọ́ gan-an. Àkòrí fídíò náà ni Bó O Ṣe Lè Borí Ẹni Tó Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ Láìbá A Jà.”
Fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́rin yìí wà lórí ìkànnì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn jw.org, ní èdè tó lé ní igba ó lé ọgọ́rin [280]. Ó tún wà ní èdè àwọn adití tó ju ọgbọ̀n [30] lọ.
Natalia Cárdenas Zuluaga, tó jẹ́ alábòójútó ètò tí wọ́n ṣe fún Ìlera Ọpọlọ Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ ní Yunifásítì CES lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà sọ pé: “Mo fẹ́ràn fídíò yẹn gan-an. Àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ kí n sọ bẹ́ẹ̀ rèé. Lórílẹ̀-èdè mi, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé táwọn ọmọ bá sọ fáwọn òbí wọn pé ẹnì kan ń bá àwọn jà, ṣe ni wọ́n á sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe tiwọn pa dà. Lójú tèmi, àwọn àbá tó wúlò ni fídíò yẹn fún àwọn ọmọ tó nírú ìṣòro yìí. Bákan náà, fídíò yẹn jẹ́ ká rí òtítọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro nípa ìṣòro híhalẹ̀ mọ́ni yìí: Ìyẹn ni pé kò sẹ́ni tí wọn ò lè halẹ̀ mọ́ torí pé onítọ̀hún kàn yàtọ̀ sáwọn tó kù lọ́nà kan tàbí òmíràn. Táwọn ọmọ bá fi èyí sọ́kàn, o máa jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀, wọn ò sì ní máa yọra wọn lẹ́nu torí bí wọ́n ṣe rí tàbí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́.”
Dr. Jun Sung Hong, tó ti ń sún mọ́ àtidi ọ̀jọ̀gbọ́n ní Yunifásítì Sungkyunkwan lórílẹ̀-èdè South Korea sọ pé: “Torí pé fídíò bèbí ni fídíò yẹn, ó máa ṣèrànwọ́ pàápàá fáwọn ọmọdé táwọn míì ń halẹ̀ mọ́, á sì tún máa wù wọ́n wò. Bákan náà, mo gbà pé àwọn tó ń wò ó á tètè máa rántí ohun tí wọ́n wò torí àwọn bèbí tó wà níbẹ̀.”
Yàtọ̀ síyẹn, Dr. Shelley Hymel, tó wà lára àwọn tó dá ètò Bullying Research Network táwọn èèyàn mọ̀ kárí ayé sílẹ̀ kíyè sí i pé: “Èmí gbà pé ẹ̀kọ́ gidi ni fídíò náà máa kọ́ àwọn ọmọdé, ó sì bá ìwádìí témi náà ti ṣe mu. Fídíò yẹn máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn òbí, olùkọ́ tàbí àgbàlagbà míì tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ láti bá àwọn ọmọ yìí sọ̀rọ̀ tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́.”
Ọ̀gbẹ́ni Semonian parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ jẹ wá lọ́kàn gan-an, ó sì dá wa lójú pé àwọn àbá tó wà nínú fídíò wa máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Bá a ṣe sọ nínú fídíò náà, ó máa dáa káwọn ọ̀dọ́ wá ẹnì kan tí wọ́n fọkàn tán, tí wọ́n á máa sọ ọ̀rọ̀ wọn fún, pàápàá òbí wọn tàbí olùkọ́, tó máa tọ́ wọn sọ́nà, táá sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹni tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ò gbọ́dọ̀ bo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí i mọ́ra.”
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000