NOVEMBER 15, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Iná Runlérùnnà ní Ìpínlẹ̀ California
Ìròyìn Lọ́ọ́lọ́ọ́: Ó ṣeni láàánú pé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti rí àrídájú pé iná Camp Fire tún gbẹ̀mí arákùnrin kan tó jẹ́ ẹni àádọ́rin (70) ọdún tó wá láti ìlú Paradise, ní agbègbè àríwá ìpínlẹ̀ California.
Ó kéré tán, èèyàn méjìdínláàádọ́ta (48) ló kú látàrí iná runlérùnnà tó jó lẹ́ẹ̀mẹta ní ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló sì bà jẹ́. Èyí tó le jù nínú iná mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n ń pè ní iná Camp Fire, iná yìí ṣì ń jo lọ ní àríwá California, ó ti jó ibi tó fẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́fà (117,000) éékà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún kan (7,100) ilé ló ti run, ilé gbígbé ló sì pọ̀ jù níbẹ̀. Ní gúúsù ìpínlẹ̀ California, ẹ̀ẹ̀mejì ni iná jó, wọ́n pe ọ̀kan ní Hill Fire, ìkejì Woolsey Fire, iná méjèèjì yìí jó ibi tó fẹ̀ tó éékà ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn ó lé mẹ́rin àtààbọ̀ (94,500), ilé tó sì run tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé márùndínlógójì (435). Ìròyìn kan sọ pé, tá a bá pa orílẹ̀-èdè Belgium àti Luxembourg pọ̀, kò tíì tó gbogbo ibi tí iná jó ní ìpínlẹ̀ California.
Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni pé iná Camp Fire lé àwọn akéde tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (427) kúrò nílùú Chico àti Paradise. Ó dùn wá pé iná yẹn pa arábìnrin àgbàlagbà kan láti Ìjọ Ponderosa. A tún rí àrídájú pé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó kéré tán, mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún (94) ilé àwọn ará wa ni iná yẹn ti run, òmíì nínú wọn sì ti bà jẹ́ gidi gan-an. Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó wà nílùú Paradise náà run pátápátá.
Nǹkan bí akéde ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (420) tó ń gbé nílùú Oxnard, Simi Valley àti Thousand Oaks ló ti kúrò nílùú nítorí àwọn iná tó jó yìí. Ó ṣeni láàánú pé arákùnrin kan àti ìyá rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kú nílùú Malibu níbi tí wọ́n ti ń sá fún iná náà. Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ fi hàn pé ilé mọ́kànlélógún (21) àwọn ará wa ló bà jẹ́, tó fi mọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù méjì sílẹ̀, kí wọ́n lè pèsè ohun táwọn ará wa nílò. Àwọn alábòójútó àyíká ṣètò àwọn alàgbà láti lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn akéde tí iná yìí ṣe ní jàǹbá, kí wọ́n sì pèsè ìrànwọ́ nípa tara fún àwọn tí àjálù náà dé bá. Ní Saturday, November 10, wọ́n ṣe àkànṣe ìpàdé kan nílùú Chico fún àwọn ará tó lé ní igba àti àádọ́rin (270). Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àtàwọn alábòójútó àyíká fi Ìwé Mímọ́ fún àwọn ará ibẹ̀ níṣìírí.
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà tu àwọn ará wa tó ń kojú ìṣòro tó nira yìí nínú, kó sì fún wọn lókun. A tún gbàdúrà pé kí wọ́n máa rántí pé láìpẹ́, Jèhófà máa nu gbogbo omijé wa kúrò, á sì gbé ikú mì títí láé.—Aísáyà 25:8.