Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 14, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Iléeṣẹ́ GBI Fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àmì Ẹ̀yẹ Tó Ga Jù Torí Pé Wọ́n Kọ́ Oríléeṣẹ́ Wọn Tuntun Lọ́nà tí Kò Ní Pa Àyíká Lára

Iléeṣẹ́ GBI Fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àmì Ẹ̀yẹ Tó Ga Jù Torí Pé Wọ́n Kọ́ Oríléeṣẹ́ Wọn Tuntun Lọ́nà tí Kò Ní Pa Àyíká Lára

NEW YORK—Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà parí oríléeṣẹ́ wọn tuntun tí wọ́n ń kọ́ ní August 2016, wọ́n gba àmì ẹ̀yẹ torí pé wọn ò ṣe ohun tó ń pa àyíká lára níbi ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sílùú Warwick, ní New York. Iléeṣẹ́ Green Building Initiative (GBI), tó máa ń yẹ ilé táwọn iléeṣẹ́ míì kọ́ wò, tó sì máa ń fún wọn lámì ẹ̀yẹ, ló fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin fún gbogbo ilé méje tí wọ́n kọ́ sí Warwick, tó yege nínú àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe. Àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin yìí ni àmì ẹ̀yẹ tó ga jù tí iléeṣẹ́ yìí lè fúnni.

Shaina Weinstein, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà níléeṣẹ́ GBI ní ẹ̀ka tó ń ṣètò àbẹ̀wò sáwọn iléeṣẹ́ sọ pé: “Nínú ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé márùndínláàádọ́rin [965] ilé tá a ti yẹ̀ wò lórílẹ̀-èdè yìí, mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] péré ló gba àmì ẹ̀yẹ tó ga jù, ìyẹn àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin. Ó yani lẹ́nu gan-an pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin fún ilé méjèèje tí wọ́n kọ́ sí Warwick yẹn. Ó fi hàn pé wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ omi, iná, wọn ò sì ba àyíká jẹ́ níbẹ̀.”

Ohun tí iléeṣẹ́ GBI máa ń wò kí ilé kan tó gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes nìyí. Gbogbo ilé méje tó wà ní oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iléeṣẹ́ yìí lọ yẹ̀ wò ló gba, ó kéré tán, àádọ́rùn-ún [90] máàkì nínú ọgọ́rùn-ún [100], tó já sí pé wọ́n á gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin.

Bí iléeṣẹ́ GBI ṣe sọ lórí ìkànnì wọn, wọ́n ní “àwọn kì í fi iṣẹ́ àwọn pawó, pé ṣe làwọn máa ń gbé ọ̀nà ìkọ́lé tó dáa lárugẹ, ìyẹn ni pé káwọn èèyàn lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ lọ́nà tó dáa, kí wọ́n sì kọ́lé lọ́nà tí kò ní wu ẹ̀mí léwu tàbí kó pa àyíká lára.” Iléeṣẹ́ GBI máa ń lọ wo àwọn ilé tuntun tí iléeṣẹ́ kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́, kí wọ́n lè rí i bóyá wọ́n ṣe dáadáa. Wọ́n tún máa ń sọ fún àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ míì tó mọ̀ nípa ẹ̀ pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni táwọn ti kó jọ nígbà táwọn lọ wo ilé náà. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ náà sì máa ń lọ fojú ara wọn wo bí wọ́n ṣe kọ́ ilè náà.

David Bean, tó ń rí sí ọ̀rọ̀ bíbójú tó àyíká ní iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “A mọrírì àwọn àmì ẹ̀yẹ yìí, ó jẹ́rìí sí i pé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ sí ilé tá a kọ́ lọ́nà tí kò pa àyíká lára yìí ló ṣiṣẹ́ náà tọkàntọkàn. Ibi tó sì dáa náà ló bọ́ sí yìí, ìyẹn inú ọgbà Sterling Forest State Park.

Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́ nìyí, wọ́n gbin oríṣiríṣi ewéko márùn-ún sórí òrùlé ibẹ̀, àmọ́ wọ́n fi nǹkan tẹ́ òrùlé náà kí wọ́n tó gbìn ín kí omi má bàa máa rin wọnú ilé. Ewéko yìí máa ń sẹ́ omi òjò tó bá rọ̀ síbẹ̀ kó tó ṣàn dà nù, kó má bàa ṣàkóbá fún omi táwọn èèyàn ń lò.

Ara ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ni pé wọ́n fi àwọn igi kan sílẹ̀ lórí ilẹ̀ yẹn, wọ́n sì lo àwọn igi tí wọ́n gé níbẹ̀ fún iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Jeffrey Hutchinson, tó jẹ́ ọ̀gá tẹ́lẹ̀ ní ọgbà Sterling Forest sọ pé: “Inú mi dùn sí ohun tí wọ́n ṣe, ìyẹn bí wọ́n ṣe gé àwọn igi tó wà níbi tí wọ́n fẹ́ kọ́lé sí, tí wọ́n wá lọ là á sí pákó, tí wọ́n sì lò ó níbi ilé tí wọ́n ń kọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe dáadáa gan-an bí wọ́n ṣe kọ́ ilé yẹn lọ́nà tí kò ba àyíká jẹ́.” Shaina Weinstein náà sọ pé, Lérò tiwa, àpẹẹrẹ gidi ni ilé tí wọ́n kọ́ sílùú Warwick yẹn jẹ́, ó jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí gan-an láti kọ́lé lọ́nà tí kò ní pa àyíká lára.”

Richard Devine, tó jẹ́ alága Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé tó bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ní Warwick sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni ètò wa ti fi bójú tó àwọn ilé tá a ní sí Brooklyn kó lè máa lẹ́wà. Àmọ́ ní báyìí, ohun tá à ń wọ̀nà fún ni bá a ṣe máa bójú tó ilé dáradára tá a kọ́ sílùú Warwick yìí, tá ò ní ṣohun tó máa pa àyíká lára níbẹ̀, tá ò sì ní ba ọgbà Sterling Forest tó jẹ́ ọgbà ẹlẹ́wà jẹ́.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-845-524-3000

 

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò lò tó ìdá márùn-ún nínú ilẹ̀ tó ní éékà 253 tí wọ́n rà ní July 17, 2009, nílùú Warwick ní New York, láti kọ́ oríléeṣẹ́ wọn tuntun.

Àwọn aṣọ tó nípọn tí wọ́n tẹ́ sílẹ̀ yìí àtàwọn òkúta lóríṣiríṣi tí wọ́n dà sórí ilẹ̀ yẹn ni wọ́n fi ki ilẹ̀ náà dáadáa kí àgbàrá òjò má bàa wọ́ ọ lọ.

Ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé náà nìyí. Ara àwọn òkúta ńlá tí wọ́n wú lórí ilẹ̀ náà rè é. Irú ẹ̀ tí wọ́n wú níbẹ̀ pọ̀ gan-an, wọ́n sì tún pa dà lò ó níbi ilé tí wọ́n ń kọ́.

Kí yẹ̀pẹ̀ inú adágún omi Blue Lake má bàa ya wá sórí ilẹ̀, wọ́n fi ohun kan sí etí omi náà yí ká. Aṣọ tó nípọn tí omi ò lè wọnú ẹ̀ ni wọ́n fi ṣeé. Òkè ẹ̀ léfòó sójú omi, èyí tó kù sì wọnú omi lọ. Ohun tó jẹ́ kí aṣọ náà lè wọnú omi ni pé wọ́n so irin ńlá kan tí kò lè dógùn-ún mọ́ etí rẹ̀ nísàlẹ̀.

Inú àwọn kinní yìí ni wọ́n máa ń da ìdọ̀tí sí kí wọ́n lè gbé e lọ sí iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń tún un lò. Níbi iṣẹ́ ìkọ́lé yìí, orí ààtàn ni wọ́n máa ń da ìdọ̀tí sí. Àmọ́ ní báyìí, èyí tó pọ̀ jù lára rẹ̀ ni wọ́n máa ń gbé lọ sí iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń tún un lò.

Àwọn òṣìṣẹ́ ń gbin òdòdó sí tòsí ibi àbáwọlé oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ti ṣètò pé wọ́n máa fi àwọn igi kan àtàwọn ewéko sílẹ̀ níbi àyíká náà, wọ́n á sì gbin koríko sí gbogbo àyíká.

Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣe irin síbi tí ẹ̀rọ ńlá kan máa wà. Omi á máa gba inú ẹ̀rọ yìí, á sì máa dé ibi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jìn tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ẹsẹ̀ bàtà. Abẹ́ ilẹ̀ máa ń lọ́ wọ́ọ́rọ́, ó sì máa ń wà bẹ́ẹ̀, àmọ́ lókè ilẹ̀, nǹkan máa ń yàtọ̀ torí ó lè jẹ́ àsìkò òjò tàbí àsìkò ooru. Iṣé tí ẹ̀rọ yìí á máa ṣe ni pé, tó bá dìgbà òtútù, á máa fa ooru látinú ilẹ̀ sínú omi tó gba inú rẹ̀. Ooru yẹn lá máa mú ilé gbóná tí òtútù bá mú. Tó bá sì di àsìkò ooru, ẹ̀rọ yẹn á máa fa ooru tó bá ń tinú ilé jáde lọ sínú ilẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà retí pé ẹ̀rọ yìí máa dín nǹkan bí ìdajì owó tí wọ́n á máa ná sórí iná mọ̀nàmọ́ná kù torí àtimú kí ilé tutù tàbí mú kó gbóná.

Inú Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́ nìyí. Bí wọ́n ṣe ṣe inú ẹ̀ (bí àpẹẹrẹ, ọ̀dà tí wọ́n fi kùn ún, bí wọ́n ṣe ṣe ògiri àti òrùlé ibẹ̀) bá ohun tí iléeṣẹ́ Green Building Initiative fọwọ́ sí mu, pé kí wọ́n má lo àwọn ohun tí kẹ́míkà máa ń jáde lára rẹ̀ gan-an, tàbí tó lè wu ẹ̀mí àwọn òṣìṣẹ́ léwu lọ́nàkọnà.