Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 11, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìròyìn nípa Hurricane Irma

Ìròyìn nípa Hurricane Irma

A gbọ́ròyìn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà ní àgbègbè Caribbean àti gúúsù ìlà oòrùn Amẹ́ríkà lẹ́yìn tí ìjì líle Hurricane Irma ṣoṣẹ́.

Ó dùn wá gan-an pé arákùnrin àgbàlagbà kan nílùú Florida àti arábìnrin kan ní Georgia kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Bákan náà, àwọn arákùnrin méjì fara pa ní ìlú Tortola. Ilé àwọn ará wa tó bà jẹ́ ní gbogbo àgbègbè Caribbean lé ní ogójì [40], ó kéré tán àwọn arákùnrin wa tí iye wọn jẹ́ ogójì [40] ló ti sá kúrò nílé wọn. Àwọn ará wa ṣì ń bá iṣẹ́ nìṣó láti mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí láwọn àgbègbè míì tí ìjì yẹn ti ṣọṣẹ́.

A kẹ́dùn gan-an pẹ̀lú àwọn tí èèyàn wọn kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn míì tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàkóbá fún láwọn ọ̀nà míì. A nígbàgbọ́ pé Jèhófà á máa tù wá nínú nìṣó nípasẹ̀ ìjọ rẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 3:7.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-300