Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 8, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìròyìn Àkọ́kọ́ Nípa Ìjì Líle Tí Wọ́n Pè ní Irma

Ìròyìn Àkọ́kọ́ Nípa Ìjì Líle Tí Wọ́n Pè ní Irma

Ìjì líle kan tó mi ilẹ̀ tìtì wáyé ní September 5, 2017, ó sì wà lára àwọn ìjì líle tó lágbára jù lọ tó wáyé ní àgbègbè Òkun Àtìláńtíìkì. Ó ti ba ọ̀pọ̀ àwọn erékùṣù tó wà ní agbègbè Caribbean jẹ́. Títí di báyìí, a kò tíì gbọ́ pé ẹnì kankan nínú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣèṣe tàbí pé wọ́n kú nínú ìṣẹ̀lẹ́ yìí. Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó wà ní La Désirade, Guadeloupe; Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní St. Barts àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan ní St. Martin la gbọ́ pé ìjì líle náà bà jẹ́.

Ìjì líle náà ṣọṣẹ́ lọ́nà tó le gan-an ní erékùṣù Barbuda, bí ìdajì àwọn tó ní ilé ní erékùṣù náà ni kò nílé lórí mọ́. Gbogbo àwọn tó ń gbé níbẹ̀, tó fi mọ́ àwọn arákùnrin wa mọ́kànlá [11] ni ìjọba ti sọ fún pé kí wọ́n tètè kúrò ní àgbègbè yẹn, kí wọ́n máa lọ sí Antigua torí wọ́n fura pé ìjì líle míì tí wọ́n pè ní José tún máa jà ní agbègbè Caribbean yẹn ní òpin ọ̀sẹ̀.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ní àwọn arákùnrin tó wà lágbègbè yẹn ti ṣe kí wọ́n lè fi àwọn nǹkan kòṣeémánìí ránṣẹ́ sí àwọn ará bí ìjì líle tí wọ́n pè ní Irma ṣe ń jà lọ sí apá gúùsù Bahamas, Cuba àti gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ara ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n ti ń ṣètò ilé sílẹ̀ fún àwọn ará tó ṣeé ṣe kí ìjì náà ba ilé wọn jẹ́.

Agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000