SEPTEMBER 20, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ìjì Líle Florence Ṣọṣẹ́ ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà
Ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Florence jà lọ́pọ̀ ibi ní ìpínlẹ̀ North Carolina, South Carolina àtàwọn ìpínlẹ̀ míì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, omíyalé sì tún ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Ìgbà kan wà tí ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Florence yìí pa ó kéré tán, èèyàn méjìlélọ́gbọ̀n (32), tó sì sọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn di aláìrílégbé.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Amẹ́ríkà sọ pé kò sí ìkankan lára àwọn akéde wa tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ tàbí tó fara pa ju bó ṣe yẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjì náà lé kúrò níbi tí wọ́n ń gbé. Lóòótọ́, ìjì náà ti jà tán, síbẹ̀ àwọn ibì kan ò tíì ṣeé dé torí omi tó bo gbogbo ibẹ̀. Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe gbẹ̀yìn fi hàn pé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mọ́kànléláàádọ́ta (351) ilé àwọn ará wa pẹ̀lú Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kànlélógún (21) ni ìjì náà bà jẹ́.
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ń ṣiṣẹ́ lórí bí àwọn ará ṣe máa rí oúnjẹ, omi, ibùgbé àti ìtọ́jú ìṣègùn tí wọ́n nílò. Àwùjọ méjì kan tún wà tó ń ṣèrànwọ́ láti kó àwọn igi tó wó lulẹ̀ kúrò lágbègbè náà. Ohun tó kù báyìí ni bí wọ́n ṣe máa tún àwọn nǹkan tí omíyalé ti bà jẹ́ ṣe. Àwọn ará láwọn ìjọ tó wà níbẹ̀ àtàwọn tó wá láti ibòmíì ń yọ̀ǹda ara wọn láti bá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù náà ṣiṣẹ́. Àwọn alàgbà ìjọ àti àwọn alábòójútó àyíká tó wà níbẹ̀ sì ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tọ́rọ̀ náà kàn láti fún wọn níṣìírí.
À ń gbàdúrà fún àwọn ará wa tí nǹkan nira fún nítorí ìjì líle tó jà lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a sì ń retí ìgbà tí ‘ẹ̀rù kankan’ ò ní bà wá mọ́.—Aísáyà 12:2.