OCTOBER 17, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Ìjì Líle Michael, Ọ̀kan Lára Èyí Tó Le Jù Tó Tíì Jà Nílẹ̀ Amẹ́ríkà Ba Nǹkan Jẹ́ Lápọ̀jù
Ní October 10, 2018, ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Michael jà ní ìpínlẹ̀ Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sì ba nǹkan jẹ́ gan-an láwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ìjì yìí le gan-an, wọ́n sì sọ pé ó wà lára àwọn ìjì tó le jù tó tíì jà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tó sì ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́. Ìjì líle yìí tún pa ó kéré tán, èèyàn méjìdínlógún (18).
Ìjì líle yìí kan àwọn ará wa ní ìjọ mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún (94) àti àyíká mẹ́tàlá (13). Kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó kú nínú àjálù yìí, àmọ́ àwọn mẹ́ta fara pa. Ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (528) ilé àwọn ará wa àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) ni ìjì yìí bà jẹ́, bákan náà, ó ba iná jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kàndínlógójì (39).
Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ogójì (40) alábòójútó àyíká láti ṣètò ohun táwọn ará nílò. Iṣẹ́ yìí gba pé kí wọ́n pèsè oúnjẹ, oògùn, ilé àti omi fáwọn ará, kí wọ́n ta tapolíìnì sórí ilé wọn, kí wọ́n sì palẹ̀ mọ́ gbogbo pàǹtírí táwọn igi tó wó lu nǹkan dá sílẹ̀. Wọ́n tún ṣètò láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ wọn.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé yìí, títí kan àwọn ìṣòro tí àjálù ń fà, ń kan àwọn ará wa, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá pé á máa ran àwọn lọ́wọ́.—Sáàmù 142:5.