Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 1, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Ilé Gbígbé Méjì Ní Ilú Brooklyn

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Ilé Gbígbé Méjì Ní Ilú Brooklyn

Ní August 31, 2017, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ta ilé tó wà ní 97 Columbia Heights. Ó ti tó ọgbọ̀n [30] ọdún táwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní orílé iṣẹ́ ti ń gbé níbẹ̀. Òtẹ́ẹ̀lì kan tí wọ́n ń pè ní Hotel Margaret ni ilé yìí tẹ́lẹ̀, tòsí ibẹ̀ sì ni East River àti Manhattan skyline wà, ilé yìí tún rẹwà gan-an torí apá ibi tó wà ní àgbègbè Brooklyn Heights, ó tún ní òrùlé téèyàn lè dúró sí àti iwájú ìta ilé téèyàn lè jókòó sí láìsí ìyọlẹ́nu. Ṣáájú, ní August 11, 2017, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ta ilé míì tó wà ní 119 Columbia Heights.

Warwick, New York ni orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà báyìí.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000