Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 7, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Iná Ńlá Tí Wọ́n Pè ní Carr Ṣọṣẹ́ Nítòsí Redding, Ìpínlẹ̀ California

Iná Ńlá Tí Wọ́n Pè ní Carr Ṣọṣẹ́ Nítòsí Redding, Ìpínlẹ̀ California

Iná ńlá kan tó sọ ní July 23, 2018 ṣì ń jó nítòsí agbègbè Redding, ní ìpínlẹ̀ California títí di báyìí. Orúkọ ibi tí iná yìí ti sọ ni wọ́n fi pe iná náà, ó ti pa èèyàn mẹ́jọ, ó sì lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó lé mẹ́wàá (110,000) éékà ilẹ̀ tó ti jó, kódà àwọn ilé tó bà jẹ́ lé ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300).

Kò sí ìkankan lára àwọn akéde tó ń gbé láwọn ibi tí iná ti ṣọṣẹ́ yìí tó fara pa kọjá bó ṣe yẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé iná náà jó arákùnrin wa kan lára níbi tó ti ń fi ọkọ̀ katapílà lànà fáwọn panápaná kí wọ́n lè ríbi kápá iná náà. Bákan náà, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta ó lé mẹ́rin (454) akéde wa lọ́kùnrin lóbìnrin ni wọ́n kúrò níbi tí wọ́n ń gbé, tí wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tàbí sọ́dọ̀ àwọn ará fúngbà díẹ̀. Iná náà ba ilé ìdílé méjìlá jẹ́ lára àwọn ará wa.

Gbogbo àwọn akéde la ti gbúròó wọn, àwọn alábòójútó àyíká pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ sì ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa pèsè ohun táwọn ará nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí lásìkò wàhálà yìí.​—Òwe 17:17.