Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 6, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìròyìn Lọ́ọ́lọ́ọ́ Nípa Iná Runlé-rùnnà Tó Ṣẹ́yọ Ní California

Ìròyìn Lọ́ọ́lọ́ọ́ Nípa Iná Runlé-rùnnà Tó Ṣẹ́yọ Ní California

Wọ́n ti ń kápá iná runlérùnnà tó ń jó lọ́nà tó kàmàmà ní California. Nínú ìsọfúnni díẹ̀ tá a rí gbà látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nípa àwọn arákùnrin wa tó wà lágbègbè yẹn, kò sí arákùnrin wa tàbí arábìnrin wa kankan tó kú, àmọ́ àwọn arákùnrin mẹ́jọ ṣèṣe, àwọn ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [1,400] ló sì ti sá kúrò nílé.

Yàtọ̀ síyẹn, ilé àwọn arákùnrin wa mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [29] ló ti bàjẹ́ pátápátá. Àwọn tó sá kúrò nílé torí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí ń rí ìtọ́jú gbà látọ̀dọ̀ àwọn ará tó wà ní ìjọ àti àyíká míì tó wà nítòsí wọn, púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin wa ló sì ti pa dà sílé wọn.

Lásìkò tí iná yẹn ṣì ń ṣọṣẹ́, àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ́ ṣèbẹ̀wò sáwọn Alábòójútó àyíká, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù àtàwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá. Wọ́n tún ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó pàdánù ilé wọn sínú ìjàǹbá yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ṣe ìpàdé àkànṣe kan pẹ̀lú àwọn àyíká méjì tí àjálù yẹn dé bá gan-an kí wọ́n lè fi Bíbélì tù wọ́n nínú, kí wọn sì ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa báa lọ láti pèsè ìtùnú fáwọn arákùnrin wa tó wà nínú ìṣòro yìí.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000