Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 13, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Iná Runlé-rùnnà ní Àríwá California

Iná Runlé-rùnnà ní Àríwá California

Àwọn panápaná ṣì ń bá iná runlérùnnà jà ní Southern California, iná yìí ti jó ibi tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì àti ààbọ̀ [250,000] éékà ní àwọn àgbègbè mẹ́fà bíi Los Angeles, Riverside, San Diego, Santa Barbara, àti Ventura.

Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn akéde ọgọ́rùn-ún mẹ́rin, àti àádọ́rin lé mẹ́rin [484] ti sá kúrò nílé, wọ́n sì lọ ń gbé pẹ̀lú àwọn arákùnrin míì tàbí pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tó ń gbé ní apá ibi tí àlááfíà wà. Yàtọ̀ síyẹn, mẹ́fà nínú ilé àwọn arákùnrin wa ló jóná, ilé mẹ́ta míì sì bàjẹ́. Àwọn alàgbà àti àwọn alábòójútó àyíká ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pèsè ìtùnú fún àwọn ará wa ti àjálù náà bá, wọ́n sì tún ń bójú tó àìní wọn nípa tara.

Gbogbo ìgbà là ń gbàdúrà fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, a sì tún fojú sọ́nà fún ìgbà tí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 1:33 máa ní ìmúṣẹ: “Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000