OCTOBER 13, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
ÌRÒYÌN TÓ KỌ́KỌ́ DÉ | Iná Tó Ṣẹ́ Yọ Ní California
Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fún wa láwọn ìsọfúnni yìí nípa àwọn arákùnrin wa tí ìjàǹbá iná ṣẹlẹ̀ sí ní Northern California àti iná igbó tó ń yára ṣọṣẹ́ gan-an ní Southern California.
Northern California: Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti kàn sí àwọn alábòójútó àyíká tó wà lágbègbè Mendocino, Napa àti Sonoma, wọ́n sì sọ fún wa pé gbogbo àwọn ará wa ti kúrò níbi tó léwu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé akéde kan fara pa. Àwọn ará tó tó ọgọ́rùn-ún méje (700) ti fi ilé wọn sílẹ̀, àwọn ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) sì ti múra tán láti lọ tó bá ṣẹlẹ̀ pé ipò nǹkan burú sí i. Àwọn ará tó wà níbi tí kò séwu ti gba àwọn tó sá kúrò níbi tí ewu wà sílé wọn. A gbọ́ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba kan àti ilé àwọn ará mẹ́ta ló bà jẹ́ pátápátá. Láfikún sí i, ilé méjìlélógún (22) ló bà jẹ́ gan-an, ilé méjìlélọ́gbọ̀n (32) sì bà jẹ́ díẹ̀. Àwọn alábòójútó àyíká ń mú ipò iwájú láti fún àwọn ará ní ìṣírí àti ìtìlẹ́yìn tí wọ́n nílò.
Southern California: Lágbègbè Anaheim, ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni wọ́n ti sá kúrò nílé wọn, àmọ́ kò sẹ́nì kankan tó fara pa. Àwọn ará tó wà níbí tí kò léwu ti gba gbogbo àwọn ará yìí sílé wọn. Kò sí ilé àwọn ará tàbí Gbọ̀ngàn Ìjọba kankan tó bà jẹ́.
Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa jẹ́ “ibi gíga ààbò” fún gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn lásìkò wàhálà yìí.—Sáàmù 9:9, 10.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000