Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 26, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìròyìn Lọ́ọ́lọ́ọ́ Nípa Ibi Tí Ètò Ìrànwọ́ Dé Lẹ́yìn Ìjì Hurricane Harvey

Ìròyìn Lọ́ọ́lọ́ọ́ Nípa Ibi Tí Ètò Ìrànwọ́ Dé Lẹ́yìn Ìjì Hurricane Harvey

NEW YORK​—Lẹ́yìn tí ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Hurricane Harvey jà, tó sì sọlẹ̀ ní tòsí àgbègbè Corpus Christi ní August 25, 2017, ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ ti ń tán lára àwọn tó ń gbé nílùú Texas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìgbìmọ̀ méjì tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù ló ń darí bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ṣe máa rí ìrànwọ́ gbà.

Arákùnrin kan ń wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbì kan tí wọ́n ti ń ṣètò ìrànwọ́ ní Houston, nílùú Texas.

Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe gbàrà tí ìjì náà jà tán. Ara ibi tí wọ́n tún ṣe ni ilé àwọn akéde tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [2,300]. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan [1,000] ló ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tó ṣì ń lọ lọ́wọ́, ìyẹn kíkọ́ àwọn ilé tí ìjì náà bà jẹ́. Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìdínláàádọ́ta [48] ni wọ́n ti tún ṣe tán báyìí, àwọn ilé tí wọ́n sì ṣètò pé wọ́n máa tún ṣe láàárín oṣù díẹ̀ sí i lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti márùndínláàádọ́ta [545]. A retí pé a máa ná tó mílíọ̀nù mẹ́jọ ààbọ̀ owó dọ́là sórí iṣẹ́ tá a máa ṣe ní àdúgbò yìí nìkan, iṣẹ́ náà á sì parí títí June 30, 2018.

Láti ìparí oṣù August 2017, àwọn aṣojú ẹ̀ka méjìlélógún [22], tó fi mọ́ àwọn méje tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, ló ti ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé àwọn akéde tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ró. Àdúrà wa ni pé kí gbogbo àwọn tó ń lọ́wọ́ sí ètò ìrànwọ́ yìí rí okun gbà kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ náà yọrí.​—Nehemáyà 6:9.

Àwọn tó ń ṣètò ìrànwọ́ ní Aransas Pass, nílùú Texas.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000