MAY 15, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Òkè Ayọnáyèéfín Tó Ń Bú Gbàù ní Hawaii Ba Nǹkan Jẹ́, Ó sì Ti Lé Àwọn Èèyàn Kúrò Nílé
Láti May 3, 2018, òkè ayọnáyèéfín Kilauea tó ń bú gbàù ní Erékùṣù Ńlá Hawaii lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti lé àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) kúrò nílé wọn, ó sì ti ba, ó kéré tán, ilé mẹ́rìndínlógójì (36) jẹ́.
Ara àwọn tó ti kúrò nílé wọn ni ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin àti arábìnrin àgbàlagbà kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan gbígbóná tó ń ru jáde látinú òkè yẹn ò ba Gbọ̀ngàn Ìjọba kankan jẹ́, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó wáyé ní May 4 ba Gbọ̀ngàn Ìjọba kan jẹ́ díẹ̀.
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù àtàwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tó wà nílùú yẹn ń bójú tó àwọn akéde tọ́rọ̀ náà kàn. Tí nǹkan bá ti lójú déwọ̀n àyè kan, ìgbìmọ̀ náà máa pinnu ìrànwọ́ míì táwọn akéde náà bá tún máa nílò.
A ò dákẹ́ àdúrà lórí àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin tọ́rọ̀ kàn torí àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ yìí, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa jẹ́ odi agbára wọn lásìkò wàhálà yìí.—Náhúmù 1:7.