Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 2, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Omíyalé Ṣẹlẹ̀ ní Àárín Gbùngbùn Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Omíyalé Ṣẹlẹ̀ ní Àárín Gbùngbùn Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Lóṣù February ọdún 2018, òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá rọ̀ ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, yìnyín tó ti dì sì domi. Èyí mú kí omiyalé ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà. Àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin láwọn ibì kan ní ìpínlẹ̀ Illinois, Indiana, Kentucky, Michigan, Ohio àti Tennessee wà lára ọ̀pọ̀ àwọn tí omi yalé wọn.

Ìròyìn tá a gbọ́ látọ̀dọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni pé ogún [20] akéde tí wọ́n wà ní àyíká mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ò nílé lórí mọ́. Ó ṣeni láàánú pé òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó rọ̀ kí omi tó bẹ̀rẹ̀ sí í yalé gbẹ̀mí ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wa ní Indiana. Àpapọ̀ ilé àwọn ará wa tó bà jẹ́ jẹ́ mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57].

Àwọn alábòójútó àyíká tó wà láwọn àgbègbè yìí ń tu gbogbo àwọn akéde tí àjálù yìí kàn nínú. A ò dákẹ́ àdúrà lórí gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin tí àjálù yìí kàn, a mọ̀ pé Jèhófà máa bójú tó gbogbo àníyàn wọn.​—1 Pétérù 5:7.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéróyìnjáde, +1-845-524-3000