Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 8, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ta Ilẹ̀ Tó Wà ní 74 Adams, Ọ̀kan Lára Àwọn Ilẹ̀ Tó Ṣẹ́ Kù sí Àdúgbò Dumbo, ní Brooklyn

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ta Ilẹ̀ Tó Wà ní 74 Adams, Ọ̀kan Lára Àwọn Ilẹ̀ Tó Ṣẹ́ Kù sí Àdúgbò Dumbo, ní Brooklyn

Ní Tuesday, November 7, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ta ilẹ̀ tó wà ní 74 Adams Street, ní àdúgbò Dumbo tó jẹ́ ibi pàtàkì ní Brooklyn, nílùú New York. Ó wà lára àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ́ kù sí àdúgbò Dumbo.

Ọdún 1975 la ra ilẹ̀ náà, nígbà tó sì di ọdún 1976, a kọ́ ibì kan tí àá ti máa tún àwọn ọkọ̀ wa ṣe síbẹ̀. Lọ́dún 1990, a kọ́ ilé míì kún un, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì ti tẹ́lẹ̀. Ní báyìí, ilé tó wà lórí ilẹ̀ náà fẹ̀ díẹ̀ ju ìdajì eékà, ilẹ̀ tó sì ṣẹ́ kù lé ní eékà mẹ́ta. Òfin fọwọ́ sí i pé ilẹ̀ náà ṣeé lò fún oríṣiríṣi nǹkan, wọ́n lè máa gbé mọ́tò síbẹ̀, ó ṣeé kọ́ ilé gbígbé sí, wọ́n sì lè kọ́ àwọn ṣọ́ọ̀bù tàbí ibi ìtajà síbẹ̀.

Agbẹ́nusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000