JUNE 1, 2016
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fẹ́ Ta Ilé Tó Ṣeyebíye sí Wa Tá À Ń Pè Ní The Towers, Nílùú Brooklyn
NEW YORK—Ní May 24, 2016, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé a fẹ́ ta ilé tá à ń pè ní The Towers, tó jẹ́ ilé alájà mẹ́rìndínlógún (16) tó wà ní 21 Clark Street, ní Brooklyn Heights Historic District. Ilé ńlá nilé yìí, ó tóbi gan-an. Òtẹ́ẹ̀lì ni wọ́n fi ń ṣe tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn sì mọ̀ ọ́n mọ́ ilé gogoro tó wà ní igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lókè, tó sì ní àgbàlá yí ká. Láti àádọ́rùn-ún (90) ọdún sẹ́yìn, àgbàyanu ni ilé yìí jẹ́ láàárín àwọn ilé ńlá tó wà nílùú Brooklyn.
Òtẹ́ẹ̀lì Leverich Towers ló wà ní ilé The Towers yìí tẹ́lẹ̀, ọdún 1928 ni wọ́n sì ṣe ayẹyẹ láti ṣí i. Iléeṣẹ́ Starrett & Van Vleck tí wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká ayàwòrán ilé ló ya òtẹ́ẹ̀lì náà. Àwọn náà ló yàwòrán ilé tí iléeṣẹ́ Lord & Taylor àti Saks Fifth Avenue tí wọ́n jẹ́ gbajúgbajà nílùú New York City ń lò. Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, àwọn míì rà á, wọ́n wá ń pe ibẹ̀ ní Òtẹ́ẹ̀lì Towers. “Gbajúgbajà Òtẹ́ẹ̀lì tí Kò Lẹ́gbẹ́ ní Brooklyn” ni wọ́n ń pè é torí pé wọ́n ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ bíi tàwọn ilé tí wọ́n máa ń kọ́ nílẹ̀ Yúróòpù ìgbà yẹn, ó ní yàrá ijó ńlá kan pẹ̀lú àwọn iná aláràbarà tó máa ń wà lórí òrùlé, ó tún ní àgbàlá kan lórí àjà òkè pátápátá téèyàn á ti lè máa rí àgbègbè Lower Manhattan, New York Harbor àti afárá Brooklyn Bridge kedere.
Àmọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ ni nǹkan ń rí lọ fún òtẹ́ẹ̀lì yìí, ìgbà tó fi máa di ọdún 1970 sísàlẹ̀, wọ́n ti pa á tì, wọn ò sì tún un ṣe. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá ra ilé náà ní January 14, 1975. Ìgbà tó fi máa di ọdún 1978, wọ́n ti ṣàtúnṣe sí ilé náà kí wọ́n lè máa lò ó fún ilé gbígbé àti yàrá ìjẹun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ á máa lò. Richard Devine tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Iṣẹ́ ìtẹ̀wé tá à ń ṣe ti fẹjú gan-an. Àyè gbà wá gan-an nílé yìí bá a ṣe ń pọ̀ sí i, ó jẹ́ káwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ríbi gbé.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe tó kàmàmà sí ilé yìí lọ́dún 1995, wọ́n fẹ́ kí ẹwà àti iyì rẹ̀ tó ti ń pa rẹ́ tún pa dà yọ. Ọ̀gbẹ́ni Devine ṣàlàyé bí iṣẹ́ náà ṣe lọ, ó ní: “Láàárín ọdún 1990 sí 1999, a tún gbogbo inú ilé náà ṣe látòkè délẹ̀, a ṣàtúnṣe sí àwọn ẹ̀rọ omi tó wà níbẹ̀, a sì ṣiṣẹ́ iná níbẹ̀. A tún ṣe àtẹ̀gùn ńlá kan tó rẹwà téèyàn máa gbà sọ̀ kalẹ̀ láti ibi téèyàn máa bá wọlé sí ibi tí yàrá ìjẹun wà.”
David A. Semonian tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wa ṣàlàyé pé: “Tẹ́ ẹ bá ń gba àdúgbò Brooklyn Heights, tẹ́ ẹ wá kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé The Towers, kò sí kẹ́ ẹ má wò ó torí àwòṣífìlà ni. Iṣẹ́ kékeré kọ́ là ń ṣe kí ẹwà ẹ̀ lè máa yọ, àmọ́ àǹfààní tílé yẹn ṣe wá ju ẹwà ẹ̀ lọ, a rí i lò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti fi ṣe ilé gbígbé fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ wa.”
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000