Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwòrán ilẹ̀ tó fi agbègbè North Kivu àti Ituri hàn, níbi tí àrùn Ebola ti jà gan-an. Ọmọbìnrin kan ń fọwọ́ níbi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ àyíká ní ìlú Beni.

MAY 2, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TI KÓŃGÒ

Àrùn Ebola Ń Jà Ràn-ìn Lórílẹ̀-Èdè Congo

Àrùn Ebola Ń Jà Ràn-ìn Lórílẹ̀-Èdè Congo

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò fara rọ lórílẹ̀-èdè Congo, tí ìjà sì ń ṣẹlẹ̀, àrùn Ebola bẹ̀rẹ̀ sí í jà níbẹ̀ láti oṣù August 2018. Lágbègbè North Kivu àti Ituri, ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,088) èèyàn tó ti kó àrùn yìí, àwọn tó sì ti pa jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé márùndíláàádọ́rin (665). Ó dùn wá pé àrùn yìí jà dé ọ̀dọ̀ àwọn ará wa. Ẹ̀ka ọ́físì wa ní Congo (Kinshasa) sọ pé, àrùn yìí pa ẹni mẹ́wàá tó ti dàgbà àti ọmọdé méjì láàárín àwọn ará. Àrùn náà ran arákùnrin kan, àmọ́ ara rẹ̀ ti kọ́fẹ pa dà.

Ká lè kọ́ àwọn ará ní bí wọ́n ṣe lè dènà àrùn yìí, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Congo (Kinshasa) gba àyè lọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí láti ṣe fídíò kan pẹ̀lú àsọyé kan. Fídíò náà kọ́ni láwọn àbá tó wúlò, irú bíi pé kí wọ́n láwọn ibi téèyàn ti lè fọwọ́ káàkiri, ìyẹn la sì ṣe ní gbogbo ìjọ. Àwọn àbá tó wúlò yìí ti jẹ́ ká lè dín bí ààrùn náà ṣe ń gbilẹ̀ kù. Ohun tá a ṣe yìí mú kí àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera méjì kọ̀wé ìmọrírì sí ẹ̀ka ófíìsì wa torí àpẹẹrẹ tó dáa àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí wọ́n rí láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lásìkò tí àrùn Ebola fi ń jà.—Mátíù 5:16.

Ìgbà kan wà tí àwọn ará wa kan ò lè jáde nílé fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ láwọn ìlú kan. Kódà, torí kí àrùn yìí má bàa túbọ̀ ràn lásìkò náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì ní kí àyíká méjìlá sún àpéjọ àgbègbè wọn síwájú. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wá ṣètò pé kí àwọn ará tó wà láwọn ìjọ tọ́rọ̀ náà kàn wo fídíò àpéjọ àgbègbè tá a ti gbà sílẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, kí wọ́n má bàa pàdánù oúnjẹ tẹ̀mí.

À ń rántí àwọn ará wa ní Congo nínú àdúrà. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì ń tù wá nínú pé àsìkò kan ń bọ̀ tí àìsàn kò ní sí mọ́ rárá.—Àìsáyà 33:24.