MAY 31, 2021
ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TI KÓŃGÒ
Òkè Ayọnáyèéfín Kan Bú Gbàù Nílùú Goma, Ọ̀pọ̀ Èèyàn Sá Kúrò Nílùú
Ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti wáyé
Ìlú Goma, ní Orílẹ̀-èdè Democratic Republic of the Congo
Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé
Ní Saturday, May 22, 2021, Òkè Nyiragongo bú gbàù ní apá Àríwá Àgbègbè Kivu, nítòsí ìlú Goma. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá kúrò níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé
Ipa tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní lórí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa
Ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) àwọn akéde ló sá lọ sáwọn ìlú tó wà nítòsí
Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún márùnlélọ́gbọ̀n (35) ló sá fi ilé wọn sílẹ̀ fúngbà díẹ̀
Àwọn ilé tó bà jẹ́
Ó kéré tán, ìlé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), tó jẹ́ tàwọn ará wa ló bà jẹ́ pátá
Ètò ìrànwọ́
Wọ́n yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Ọ̀rọ̀ Àjálù láti darí ètò ìpèsè ìrànwọ́. Ìgbìmọ̀ yìí ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà tó wà ládùúgbò láti mọ bí nǹkan ṣe bà jẹ́ tó, kí wọ́n sì ṣètò ìrànwọ́ tó yẹ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin náà
Gbogbo àwọn tó kópa nínú ètò ìrànwọ́ yìí pátá ló tẹ̀ lé ìtọ́ni nípa ààbò lọ́wọ́ ààrùn COVID-19
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló pàdánù ilé wọn, inú wa dùn pé kò sẹ́nì kankan nínú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó fara pa nínú àjálù náà. A ó máa gbàdúrà fún wọn bí wọ́n ṣe ń wojú Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ lásìkò wàhálà yìí.—Náhúmù 1:7.