FEBRUARY 28, 2022
ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TI KÓŃGÒ
A Mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì Jáde Lédè Kipende
Ní February 20, 2022, a mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Kipende nínú ètò kan tá a gbà sílẹ̀. Arákùnrin Nicolas Hifinger tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Congo (Kinshasa) ló mú ẹ̀dà ti orí ẹ̀rọ jáde, àwọn akéde tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ló sì wo ètò náà. Ẹ̀dà ti orí ìwé máa jáde ní April 2022.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Kipende láwọn ọdún 1960. Nígbà yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Makanda Madinga Henri ní ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kan. Lẹ́yìn tó ka Ilé Ìṣọ́ yẹn, ó rí i pé òótọ́ lohun tó wà nínú ẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi, ó sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́dún 1979, wọ́n dá ìjọ àkọ́kọ́ tó ń sọ èdè Kipende sílẹ̀ nílùú Kiefu.
Ìtumọ̀ Bíbélì yìí máa ran àwọn ará wa lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ àti nígbà tí wọ́n bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Hifinger ṣàlàyé pé Bíbélì yìí “péye, ó sì rọrùn kà,” àti pé “ó dá orúkọ Jèhófà pa dà sí gbogbo ibi tó wà nínú Bíbélì àtijọ́.”
Àdúrà wa ni pé kí ìtumọ̀ Bíbélì yìí mú káwọn ará wa máa ‘so èso nínú gbogbo iṣẹ́ rere, kí ìmọ̀ tó péye tí wọ́n ní nípa Ọlọ́run sì máa pọ̀ sí i.’—Kólósè 1:10.