JUNE 3, 2021
ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TI KÓŃGÒ
A Mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde ní Èdè Alur
Ní May 30, 2021, a mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Alur. Arákùnrin Hugues Kabitshwa tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ìlú Kóńgò (Kinshasa) ló mú Bíbélì yìí jáde ní ẹ̀dà ti orí ẹ̀rọ, nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wọ́n gbà sílẹ̀.
Àwọn ìsọfúnni pàtàkì nípa iṣẹ́ náà
Àárín Gbùngbùn Áfíríkà ni wọ́n ti ń sọ èdè Alur, ní pàtó lápá àríwá ìlà oòrùn Orílẹ̀-èdè Democratic Republic of the Congo àti ilẹ̀ Uganda tó wà lágbègbè ibẹ̀
Wọ́n fojú bù ú pé ó tó èèyàn mílíọ̀nù kan, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje àti márùndínlógójì (1,735,000) tó ń sọ èdè Alur
Àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (1,500) ló ń sìn láwọn ìjọ àti àwùjọ méjìdínláàádọ́ta (48) tó ń sọ èdè Alur
Oṣù méjìlá làwọn atúmọ̀ èdè mẹ́fà fi ṣe ìtúmọ̀ Bíbélì yìí
Arákùnrin Christian Belotti tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ìlú Kóńgò (Kinshasa) sọ pé: “Àwọn akéde tó ń sọ èdè Alur máa gbádùn kíka Bíbélì yìí. Ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ dáadáa, á sì jẹ́ káwọn míì náà lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”—Lúùkù 24:32.
Ó dá wa lójú pé Bíbélì tá a mú jáde láìpẹ́ yìí máa ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́ láti máa kéde “ìhìn rere àìnípẹ̀kun.”—Ìfihàn 14:6.