JULY 18, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TI KÓŃGÒ
Àwọn Ará ní Àríwá Ìlà Oòrùn Kóńgò Sá Torí Àwọn Tó Ń Jà
Láti December 2017, ìjà abẹ́lé tó ń wáyé láàárín àwọn Hema àti Lendu lágbègbè Ituri ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò ti yọrí sí ikú ọ̀pọ̀ èèyàn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni ò sì nílé lórí mọ́. Ṣe ni ìjà yìí ń le sí i, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin sì wà lára àwọn tó ń fara gbá àbájáde rẹ̀.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ogun lé wá sí Kóńgò, tó fi mọ́ àwọn akéde igba ó dín mẹ́jọ (192) tó ń gbé ní ibùdó méjì nítòsí ààlà Kóńgò, ti sá lọ sí Ùgáńdà láti forí ara wọn pa mọ́. Nígbà tó fi máa di June 2018, ẹgbẹ̀rún kan ó lé méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (1,098) Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti sá kúrò níbi táwọn èèyàn ti ń jà lọ sí Bunia, tó jẹ́ olú-ìlú Ituri. Ó dùn wá pé tọkọtaya kan àtàwọn ọmọ kékeré mẹ́ta táwọn òbí wọn ti ṣèrìbọmi ṣaláìsí, torí pé wọ́n ṣàìsàn. Àmọ́ àwọn tó ń para wọn nípakúpa náà ò rí ìkankan nínú àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin pa.
Àwọn jàǹdùkú ti fọ́ ilé ọ̀pọ̀ àwọn ará tó sá lọ, ṣe ni wọ́n tiẹ̀ jó àwọn ilé kan kanlẹ̀. Bákan náà, wọ́n ba ọ̀pọ̀ irè oko àwọn ará náà jẹ́, bẹ́ẹ̀ torí kí wọ́n lè fi gbọ́ bùkátà ni wọ́n ṣe gbìn wọ́n.
Àtìgbà tí ìjà náà ti bẹ̀rẹ̀ làwọn akéde tí kò sí níbi tí wọ́n ti ń jà ti ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará wọn tọ́rọ̀ yìí kàn. Àwọn kan gbé ọkọ̀ wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè fi kó àwọn ará lọ síbi tí kò séwu (wo àwòrán ìbẹ̀rẹ̀). Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà tíye wọn jẹ́ igba ó lé márùn-ún (205) láti ìlú Bunia fi owó àti oúnjẹ ránṣẹ́, kódà wọ́n gba àwọn ará wọn sílé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́. Lóòótọ́, ibùdó méjì tó tóbi déwọ̀n àyè kan wà nílùú Bunia táwọn tí ogun lé wá lè dé sí, àmọ́ gbogbo àwọn akéde tó sá kúrò ní Kóńgò làwọn ará wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bunia ti gbà sílé.—Òwe 17:17.
Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Kóńgò ṣètò ìgbìmọ̀ kan tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù, ìgbìmọ̀ yìí sì ti pèsè àwọn ohun kòṣeémáàní fáwọn ará wa. Aṣojú kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì tún bẹ àwọn ará tọ́rọ̀ kàn wò, ó sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé wọn ró.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tó sá lọ sí Bunia àtàwọn ibòmíì ò nílé tara wọn, síbẹ̀ wọ́n ń kóra jọ láti jọ́sìn pẹ̀lú àwọn ìjọ tó wà lágbègbè náà, wọ́n sì ń fìtara wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Láti February sí April 2018, ó lé ní igba àti àádọ́rin (270) èèyàn táwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi táwọn tí ogun lé kúrò nílùú ń gbé.
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fún àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin lórílẹ̀-èdè Kóńgò ní ìbàlẹ̀ ọkàn, kó sì bù kún ìsapá tá à ń ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn akéde tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Gbogbo wa là ń retí ọjọ́ tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé, táá sì pèsè ààbò tó máa wà títí láé àti “ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà” fún gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà.—Aísáyà 32:17, 18.