Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 16, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TI KÓŃGÒ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣèrànwọ́ Fáwọn tí Omi Yalé Wọn ní Kóńgò

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣèrànwọ́ Fáwọn tí Omi Yalé Wọn ní Kóńgò

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará wọn àtàwọn míì tí omi yalé wọn ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò. Ọ̀sẹ̀ December 26 ni omíyalé yìí ṣẹlẹ̀ nílùú Boma, tó wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé àádọ́rin [470] kìlómítà sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìlú Kinshasa.

Mọ́kàndínlógójì [39] ni ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí omi yalé wọn, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì gbẹ̀mí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Yàtọ̀ síyẹn, ilé márùn-ún tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí ló bà jẹ́ pátápátá, ilé márùn-ún míì sì bà jẹ́ díẹ̀.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Kóńgò kó oúnjẹ àti aṣọ ránṣẹ́ sáwọn Ẹlẹ́rìí tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí lápá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n lè rí nǹkan tọ́jú ara wọn ní kíákíá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wà nílùú Matadi àti Muanda, tó wà ní nǹkan bí ọgọ́rin [80] kìlómítà sílùú Boma, tún ṣèrànwọ́ fáwọn ará wọn láwọn ọ̀nà míì.

Láti oríléeṣẹ́ wa ní New York ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bójú tó bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ní Kóńgò, wọ́n ń lò lára owó táwọn èèyàn fi ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò: Robert Elongo, +243-81-555-1000